ỌYỌ: WỌN YỌ ỌMỌ ALAO AKALA NIPO, LO BA GBA ILE ẸJỌ LỌ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, February 21, 2019

ỌYỌ: WỌN YỌ ỌMỌ ALAO AKALA NIPO, LO BA GBA ILE ẸJỌ LỌ

Ọla Eyitayọ, Ọyọ 

Titi dasiko ta a ṣakojọpọ iroyin yi tan, ko tii sẹni to le sọ ibi ti wahala naa yoo pada ja si latari bi wọn ṣe yọ ọmọ Gomina ana nipinlẹ Ọyọ, Alao Akala, iyẹn Ọlajuwọn nipo gẹgẹ bi alaga ijọba ibilẹ Ariwa Ogbomọṣọ.

Idi ni pe Ọlamijuwọnlọ, tii se ọmọ bibi Ọtunba Adebayọ Akala, ti kin baba rẹ lẹyin pe ijọba ipinlẹ Ọyọ ko ni atilẹyin ofin lati yọ oun nipo.

Ọlamiju salaye pe ara lo n ta ẹgbẹ oṣelu APC, nitori pe oun pada sẹgbẹ baba oun, tii se PDP, ti kanselọ mẹrin ninu mẹjọ si wa lẹyin oun.

O fikun pe awọn eeyan ilu Ogbomọṣọ nikan lo lee yọ oun nipo, kii ṣe Kọmisana, bẹẹ si ni ko sẹlẹ ri, ki Kọmisana maa bura fun alaga ijọba ibilẹ.

O wa fọwọ gbaya pe ile ẹjọ ni yoo ba oun ati ijọba ipinlẹ Ọyọ da si ọrọ naa.


WAHALA YOO ṢẸLẸ L'ỌYỌ – ALAO AKALA

Ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu BBC Yoruba, oludije gomina fun ẹgbẹ oselu ADP nipinlẹ Ọyọ, Ọtunba Adebayọ Akala figbe ta pe ti ẹgbẹ oselu APC ba fi yọ ọmọ oun nipo, wọn kan fẹ da ija igboro sil ni.

Akala, to ni oun yoo jaa nija ni, tun salaye pe, ẹgbẹ oṣelu APC ko tẹle ofin pẹlu bi wọn se kede pe awọn ti yọ ọmọ oun nipo alaga ijọba ibilẹ.

Akala ni awọn eeyan Ogbomọṣọ nikan lo lee yọ alaga ijọba nipo, kii se Kọmisọna kankan pẹlu afikun pe ki lo de to jẹ igba ti ọmọ oun kuro ni APC, ni tiẹ yatọ si ti ara yoku.

Alao Akala tun ni arifin nla ni bawọn eeyan kan se npariwo pe oun n sisẹ fun Ṣeyi Makinde to jẹ oludije gomina fẹgbẹ PDP.
 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI