Gomina ipinlẹ Kaduna, Mallam
Nasil El-Rufai ti figbe ta pe eeyan mẹrindinlaadọrin ni awọn gende agbebọn
sekuta nijọba ibilẹ Kajuru.
El Rufai, ninu atẹjade kan to
fisita ni, ọmọde mejilelogun ati obinrin mejila lo fori sọta isẹlẹ ipaniyan
naa.
Amọ sa, atẹjade naa ko
salayeohun to fa sababi isẹlẹ naa.
Atẹjade naa wa leri leka pe,
gbogbo awọn eeyan to ba lọwọ ninu isẹlẹ isekupani yii ni yoo finmu kata ofin.
Loju opo twitter re, @elrufai,
gomina ipinlẹ́ Kaduna foju laifi wo isẹlẹ naa, to si n fewe ọmọ mọ awọn eeyan
agbegbe naa leti lati mase gbẹsan.
- BBC
No comments:
Post a Comment