IDIBO 2019: A FI KIJỌBA APAPỌ ORILEEDE NAIJIRIA ṢAGBATẸRU ORIN MI BI WỌN KO BA FẸ KI WAHALA ṢẸLẸ LASIKO IDIBO - ỌRUNṢỌLA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, February 22, 2019

IDIBO 2019: A FI KIJỌBA APAPỌ ORILEEDE NAIJIRIA ṢAGBATẸRU ORIN MI BI WỌN KO BA FẸ KI WAHALA ṢẸLẸ LASIKO IDIBO - ỌRUNṢỌLA

Kii ṣe iroyin tuntun mọ pe ọkan pataki lara awọn orin to ba oṣelu asiko yi lọ ni 'Ko Gba Gidigbo' ati 'Ibo Ifẹ' ti gbajumọ olorin nni, Ọgbẹni Olufẹmi Ọrunṣọla kọ lati fi gba awọn araalu, paapaa awọn oludibo ati oloṣelu lamọnran.


Ni kete ti Aarẹ Muhammadu Buhari b'awọn ọmọ orileede Naijiria sọrọ tan laarọ onii Fraide pe ki wọn jade sita rẹpẹtẹ lati lọọ dibo fun ẹni to wu wọn naa ni gbajumọ olorin yi, Ọrunṣọla t'awọn eeyan tun n pe ni Àwé pariwo ti ẹ naa sita pe afi kijọba apapọ orileede yi tete ṣagbatẹru orin oun meji tuntun naa bi wọn ko ba fẹ k'awọn eeyan fa wahala lasiko idibo.

Awọn orin tuntun 'Ko Gba Gidigbo' ati 'Ibo Ifẹ' naa ti Àwé ṣẹṣẹ gbe jade sita laipẹ yi lo ti jẹ k'awọn eeyan mọ pe oṣelu kii ṣe tipa-tikuuku, ko si gba wahala kankan, nitori naa k'awọn eeyan ṣe jẹjẹ.

Ninu awọn orin naa lo ti ni ko si oloṣelu kan to ṣe e ku nitori ẹ, idi niyii to fi sọ pe idibo ko yẹ ko gba nnkan t'awọn araalu yoo maa fi ada tabi ibọn le ara wọn kaakiri.

Bẹẹ lo tun parọwa s'awọn oludibo pe ki wọn fi ifẹ atọkanwa duro ti ibo wọn.

Ọrunṣọla ti wọn tun maa n pe ni Ọmọba-Ọrun sọ pe ọgbọn, imọ ati oye to wa ninu awọn orin naa to nnkan tijọba apapọ le fi ran orin naa lọwọ, paapaa bo ṣe jẹ pe titilai ni orin naa fi wulo.

Kaakiri ori ẹrọ ayelujara ni lawọn orin naa ti n mi titi, t'awọn ileeṣẹ redio kọọkan si ti n lo o, o ni bijọba ba paṣẹ fawọn ileeṣẹ igbohunsafẹfẹ kaakiri orileede yi lati maa lo o ki idibo to o de, yoo tubọ ṣanfaani fawọn oludibo lati jade sita dibo.

O wa a kadi ọrọ ẹ nilẹ pe kijọba tete ṣagbatẹru orin naa bi ko ba fẹ k'awọn eeyan fa wahala lọjọ idibo, nitori pe bi wọn ba gbọ orin naa, ọkan awọn to fẹ ẹ da wahala silẹ yoo ti yi pada ko too di ọjọ idibo tii ṣe ọla Satide.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI