IFẸ AWỌN OṢIṢẸ IJỌBA LO MU KI N ṢIṢẸ FUN ẸGBẸ OṢELU APC NIPINLẸ ỌṢUN - OMIṢORE - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, February 22, 2019

IFẸ AWỌN OṢIṢẸ IJỌBA LO MU KI N ṢIṢẸ FUN ẸGBẸ OṢELU APC NIPINLẸ ỌṢUN - OMIṢORE

Folukẹ Aduragbemi, Ọṣun 

Igbakeji gomina tẹlẹ nipinle Ọṣun, Ọtunba Iyiọla Omiṣore ti sọ pe lati le maa pariwo igbayegbadun awọn oṣiṣẹ ijọba nipinlẹ Ọṣun si eti Gomina Gboyega Oyetọla loun ṣe gba lati fi ẹgbẹ oṣelu SDP silẹ, toun si darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu APC.

Omiṣore, ẹni to dupo gomina ipinlẹ naa lọdun to kọja yi labẹ asia ẹgbẹ oṣelu SDP, ko too di pe o ṣiṣẹ pọ pẹlu ẹgbẹ APC lasiko atundi ibo ṣalaye ọrọ yii nile rẹ niluu Ile-Ife.

O ni oun ko fẹ ki awọn araalu, paapaa awọn oṣiṣẹ ijọba atawọn oṣiṣẹfẹyinti ri igbesẹ oun lati ṣiṣẹ pọ pẹlu APC bii pe ṣe loun fi ọbẹ ẹyin jẹ wọn niṣu.

Omisore ni ọkan pataki lara erongba ẹgbẹ oṣelu SDP latigba ti wọn ti da a silẹ ni lati mu aye rọrun fun awọn oṣiṣẹ ijọba, oun si gbe e siwaju ẹgbẹ PDP ati APC lasiko ti wọn nilo iranlọwọ oun fun atundi ibo loṣu kẹsan ọdun to kọja.

O ni ẹgbẹ oṣelu APC nikan lo ṣetan lati gba ọrọ naa yẹwo, ti wọn si ṣeleri lati mu ọrọ awọn oṣiṣẹ ijọba pẹlu awọn oṣiṣẹfẹyinti lokunkundun.

Ọtunba wa fi da gbogbo awọn oṣiṣẹfẹyinti atawọn oṣiṣẹ ijọba loju pe iya kankan ko ni jẹ wọn labẹ iṣejọba Gomina Oyetọla, o ni oogun oju wọn ko nii gbẹ, bẹẹ nijọba ko nii fi ẹtọ wọn dun wọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI