IDIBO GOMINA: WỌN FẸẸ YẸYẸ GBOYEGA ISIAKA NITA GBANGBA, ORI LO KO O YỌ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, February 9, 2019

IDIBO GOMINA: WỌN FẸẸ YẸYẸ GBOYEGA ISIAKA NITA GBANGBA, ORI LO KO O YỌ

Bọsun Ọlaniyi, Abeokuta

Kani kii ṣe pe adije sipo gomina ipinlẹ Ogun labẹ ẹgbẹ oṣelu ADC, Ọmọba Gboyega Nasiru Isiaka duro daadaa ni, o ṣee ṣe kawọn ọta ti fẹyin ẹ gbolẹ lọjọ Fraide ana nibi ipade itagbangba fawọn oludije sipo gomina nipinlẹ naa, eyi ti ileeṣẹ BBC Yoruba ṣagbekalẹ ẹ.

Ohun ta a gbọ pe ni pe awọn kan ninu awọn ẹgbẹ alatako ni wọn dide lati wa ọna ti wọn yoo gba yẹyẹ ọkunrin naa, ki wọn le fi gbe ẹni tawọn nifẹ si larugẹ.

Oriṣiriṣi ibeere la gbọ pe wọn beere lọwọ Gboyega Isiaka, to si dahun gbogbo ẹ daadaa, ko da, tawọn eeyan tun patẹwọ fun un, eyi ti wọn ni ko tẹ awọn alatako ẹ kan lọrun.

AWIKONKO gbọ pe bi wọn ṣe fun ẹnikan laaye lati bere ibeere to gbẹyin lọwọ Isiaka ti wọn tun n pe ni GNI, si iyalẹnu, akanda eeyan lẹni naa jẹ, idi ni yi ti wọn fi gba a laaye lati sọrọ.

Kaka ki ọkunrin naa beere ibeere, ṣe lo fẹsun ibaniloju jẹ kan GNI, to sọ pe GNI ko loju aanu rara, nitori pe lọjọ kan loun daa duro ninu Ibara Estate pe ko gbe oun de iwaju OPIC, iyẹn niluu Abẹokuta, ṣugbọn kaka ko gbe oun, ṣe lo yi gilaasi mọto ẹ soke, to si salọ foun.

Ọpọ awọn to gbọ ẹsun yi ni wọn pariwo sita nitori pe ọrọ naa ṣe wọn kayeefi rẹpẹtẹ, ko da a, loju ẹsẹ ni GNI ti koro oju nibi to duro sii, to si han gbangba loju ẹ pe inu bajẹ gidigidi si ọrọ naa.

Nigba to n fesi si ẹsun naa, GNI sọ pe oun ko tiẹ figba kan ri ranti asiko tabi ọjọ ti ẹni naa n sọ, nitori pe ko ṣee ṣe keeyan da oun duro lori irin lai duro, depodepo wi pe koun duro, ki ẹni naa wa beere fun iranlọwọ, koun ma wa ṣen e, GNI sọ pe ọrọ naa kii ṣe otitọ.

Bakan naa lo beere pada lọwọ ẹni to beere ibeere yi pe ṣe nigba ti ẹni naa da oun duro, ṣe oun duro ni, ati pe ṣe lẹyin toun gbọ nnkan to fẹẹ sọ tan loun ṣẹṣẹ kuro niwaju ẹ, ṣugbọn ti ọkunrin naa ko pada dahun.

Bẹẹ lo tun beere lọwọ ọkunrin akanda eeyan naa pe bawo lo ṣe mọ pe ọna awọn papọ, ati pe bawo lo ṣe mọ pe OPIC loun n lo.

Loju ẹsẹ lawọn to wa ninu gbọngan ayẹyẹ ti eto naa ti waye ni wọn bu ẹnu atẹ lu ọrọ ti ọkunrin naa sọ, to si mu kawọn kan maa sọ pe awọn ẹgbẹ alatako ni wọn ran an wa lati wa yẹyẹ nita gbangba, ṣugbọn ti Ọlọrun ko gba fun wọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI