Ó MÀ ṢE O: ÀWỌN AGBÁBỌ́Ọ̀LÙ MẸ́WÀÁ LÓ KÚ SÍNÚ ÌJÀMBÁ ÍNÁ NÍ BRAZIL - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, February 9, 2019

Ó MÀ ṢE O: ÀWỌN AGBÁBỌ́Ọ̀LÙ MẸ́WÀÁ LÓ KÚ SÍNÚ ÌJÀMBÁ ÍNÁ NÍ BRAZIL

Àwọn agbábọ́ọ̀lù ọ̀jẹ̀wẹ́wẹ́ mẹ́wàá tí ọjọ́ orí wọn kò tó ogún ọdún ni wọ́n pàdánù ẹ̀mí wọn nínú iná kan tó sẹ́yọ ní ibùdó ìgbaradì ti Ẹgbẹ́ Agbábọ́ọ̀lù Flamengo ní ìlù Brazil.

Iná náà èyí tí wọn kò mọ bí ó ṣe sẹ́yọ ni ó bẹ̀rẹ̀ ní ọwọ́ aago márùn-ún fẹ̀ẹ̀rẹ̀ ní àsìkò tí àwọn agbábọ́ọ̀lù náà ń sùn lọ́wọ́ tí ó sì ṣe ikú pa agbábọ́ọ̀lù mẹ́wàá tí àwọn mẹ́ta mìíràn sì farapa.

Gẹ́gẹ́ bí àwọn olóri ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù náà ṣe sọ, àwọn agbábọ́ọ̀lù náà tí wọ́n bá ìsẹ̀lẹ̀ náà lọ ni ọjọ́ orí wọn wà láàárín mẹ́rìnlá àti mẹ́tàdínlógún tí àwọn mẹ́ta tí wọ́n farapa náà ti ń gba ìtọ́jú nílé ìwòsàn kan.


Gómìnà ìpínlẹ̀ Rio de Janeiro, Wilson Witzel ti kéde ọjọ́ mẹ́ta láti fi ṣọ̀fọ̀ àwọn tí wọ́n bá ìjàmbá náà lọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI