IDIBO KU ỌLA: AKỌWE IJỌBA IPINLẸ OGUN KAGBAKO IJAMBA MỌTO, BẸẸ NI OLUDAMỌNRAN GOMINA AMOSUN PADANU ẸMI Ẹ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, February 22, 2019

IDIBO KU ỌLA: AKỌWE IJỌBA IPINLẸ OGUN KAGBAKO IJAMBA MỌTO, BẸẸ NI OLUDAMỌNRAN GOMINA AMOSUN PADANU ẸMI Ẹ


Bọsun Ọlaniyi, Abeokuta
 
Titi dasiko ta a ṣakojọpọ iroyin yi tan, ẹsẹ kan aye, ẹsẹ kan ọrun ni akọwe ijọba ipinlẹ Ogun, Amofin Taiwo Adeoluwa wa nibi to ti n gba itọju nile iwosan tijọba apapọ, Federal Medical Centre to wa ni Idi-Aba, niluu Abẹokuta.

Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, agbegbe Ṣiun si Kọbapẹ, tii ṣe ijọba ibilẹ Ọbafẹmi Owode, loju ọna to lọ lati ilu Abẹokuta si Ṣagamu nijamba mọto ti akọwe ijọba yi wa ti ṣẹlẹ, ta a si gbọ pe ọkan lara awọn Oludamọnran fun Gomina Ibikunle Amosun, Ọmọba Adebiyi Adesanya naa padanu ẹmi loju ẹsẹ.

Bo tilẹ jẹ pe ko tii sẹni to le sọ pato nnkan to ṣokunfa ijamba burku naa, ṣugbọn ohun ta a gbọ ni pe ibi ipade kan ni Amofin Adeoluwa atawọn isọngbe ẹ, to fi mọ ọkan lara awọn oludamọnran fun Gomina Amosun yi ti m bọ.

Ọgbẹni Clement Ọladele to jẹ agbenusọ fun ajọ ẹṣọ oju popona fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, oun lo si jẹ ko ye wa pe awọn oṣiṣẹ wọn lo gbe awọn eeyan naa lọ si ọsibitu FMC fun itọju pajawiri, ti wọn si ti gbe oku Adebiyi wọ mọṣuari lẹsẹkẹsẹ.

Titi dasiko ta a ṣakojọpọ iroyin yi tan, a gbọ pe inu ibanujẹ ọkan lawọn mọlẹbi akọwe ijọba ati oludamọnran fun Gomina Amosun wa bayii, ta a si gbọ pe Gomina Amosun funra ẹ ti yọju si ọsibitu naa lati bawọn kẹdun.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI