O TAN O: WỌN NI AJỌ INEC KO TII DE WỌỌDU ADARI IPOLONGO ẸGBẸ OṢELU APM NIPINLẸ OGUN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, February 23, 2019

O TAN O: WỌN NI AJỌ INEC KO TII DE WỌỌDU ADARI IPOLONGO ẸGBẸ OṢELU APM NIPINLẸ OGUN

Titi dasiko tá a sakojọpọ iroyin yi tan laago mẹwàá kọja isẹju marun un, iyalẹnu ni wọn loo jẹ pe ko tii si aṣoju àjọ eleto idibo ni wọọdu karun un, yuniiti kẹsán an (ward 5, unit 9) nijọba ibilẹ Abẹokuta North.

Agbegbe idibo ti wọn loo jẹ ti adari ipolongo ẹgbẹ oṣelu APM nipinlẹ Ogun, Alaaji Ṣarafadeen Tunji Iṣọla.

Ṣe lawọn oludibo kan duro, ti wọn gbe ọwọ le igbọn wọn, ti wọn sì n reti àjọ INEC, ki wọn lee dibo.

O ṣeni laanu pe awọn wọọdu to sunmọ agbegbe naa lawọn eeyan ti bẹrẹ sii dibo ni nnkan bi ọgbọn isẹju sẹyìn.

Nigba to n b'AWIKONKO sọrọ, Alaaji Tunji Iṣọla sọ pe iyalẹnu lo jẹ foun pe ajọ INEC kan dawọn eeyan duro lasan ni.

O loun mọ pe awọn oṣiṣẹ INEC maa wa, ṣugbọn asiko naa loun ko mọ. O wa rọ àjọ naa pe ki wọn tete de ki asiko too lọ pẹlu bi àjọ naa ṣe sọ pe aago meji ni idibo yoo pari.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI