KAṢAMU, DAPỌ ABIỌDUN ATI DIMEJI BANKỌLE SA NIBI IPADE ITAGBANGBA TI BBC GBE KALẸ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, February 8, 2019

KAṢAMU, DAPỌ ABIỌDUN ATI DIMEJI BANKỌLE SA NIBI IPADE ITAGBANGBA TI BBC GBE KALẸ

https://ichef.bbci.co.uk/news/660/cpsprodpb/16AF5/production/_105571929_dddddbbbb.jpgBọsun Ọlaniyi, Abeokuta

Àsà àti ìṣe BBC ni láti máa fún gbogbo ènìyàn ní pèpéle kan náà, ìdí niyìí tí wọ́n ṣe ti ṣáájú kọ̀wé pe gbogbo àwọn olùdíje sípò gómìnà tí àwọn ènìyàn sọ pé àwọn ń fẹ́ láti rí níbi ìpàdé ìtagbangba ìpínlẹ̀ Ogun. ẹgbẹ́ òṣèlú méje la gbọ pe BBC fiwe pè.

PDP: Buruji Kashamu

APM: Adekunle Akinlade

ANN: Ademola Ogunbanjọ

ADP: Dimeji Bankole

APC: Dapo Abiodun

ADC: Gboyega Nasiru Isiaka

SDP: Rotimi Paseda

Àwọn olùdíje mẹ́ta ló kọ̀ tí kò wá tí wọn kò sì kọ̀wé ránṣẹ́ pé àwọn kò ni wá, àwọn olùdíje náà ni Dimeji Bankole ti ẹgbẹ́ òṣèlú ADP, Dapo Abiodun ti ẹgbẹ́ òṣèlú APC àti Buruji Kashamu ti ẹgbẹ́ òṣèlú PDP lẹ́yin ti wọn ti sọ pé àwọn yóò yọjú.

Nínú àwọn olùdíje ti kò yọju yìí sí fi dá ilé iṣẹ́ BBC lóju titi dí alẹ ọjọ́bọ̀ pé àwọn ń bọ sùgbọn titi tí ìròyìn yìí fí ń jáde à kò ti gbọ́ ìdí ti wọn kò fi péjú síbẹ̀

Ẹwẹ, gbogbo awọn oludije to yọju lo wu awọn eniyan lori pẹlu gbogbo alakalẹ aato wọn lọlọkan o jọkan ti wọn ni awọn yoo gbe ṣe bi awọn ba di gomina ipinlẹ Ogun.
- BBC

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI