PAṢEDA ṢEPE FAWỌN OLOṢELU TO N DA NAIJIRIA RU - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, February 8, 2019

PAṢEDA ṢEPE FAWỌN OLOṢELU TO N DA NAIJIRIA RU

Bọsun Ọlaniyi, Abeokuta

Adije sipo gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu Social Democratic Party, SDP, Ọtunba Rotimi Paṣeda ti bu epe rabande-rabande fawọn oloṣelu to n da Naijiria, paapaa ipinlẹ Ogun laamu, ti wọn ko jẹ kitesiwaju gidi wa fawọn araalu.

Nibi ipade itagbangba pẹlu awọn gomina ipinlẹ naa, eyi ti ileeṣẹ BBC Yoruba gbe kale niluu Abẹokuta lonii, ninu gbọngan ile ikawe ti Ọbasanjọ Library, OOPL.

Ọtunba Rotimi Paṣeda to dije sipo gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu Unity Party of Nigeria, UPN lọdun 2015, ṣugbọn to fẹẹ gba ẹgbẹ oṣelu SDP jade bayii lo ṣepe nla yi lasiko to n kadi ọrọ ẹ nilẹ.

O ni oun gbadura pe ki Ọlọrun ṣe idajọ to tọ fawọn oloṣelu pẹlu bi wọn ṣe n ṣejọba lorileede yi, ati pe ki Ọlọrun pin onikaluku wọn ni ere iṣẹ ọwọ wọn latari iṣjọba wọn.

O tun ṣo pe oloṣelu to n dije dupo, to ba n gbiyanju lati ṣejọba baṣubaṣu ni ki wọn jeere iṣẹ ọwọ wọn pẹlu arọmọdọmọ wọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI