Iyawo Gomina ipinlẹ Ekiti, Erelu Bisi Fayẹmi ti ṣabẹwo sawọn agbaagba l’ẹka ẹsin lati rawọ ẹbẹ si wọn fun idibo apapọ orileede yi to n bọ lọjọ Satide ọsẹ yi.
Oni tii ṣe Wẹside ni Erelu
Fayẹmi gbe abẹwo naa lọ sọdọ awọn olori ẹlẹsin Kristẹni ti wọn pe ni Women's Wing of Christian Association of Nigerian (WOWICAN)
ati tawọn Musulumi ti wọn pe ni Federation of
Muslim Women's Association of Nigerian (FOMWAN) fun ti idibo to n bọ lọjọ
satide ati ọjọ keji oṣu kẹta ọdun yi.
Lara awọn to tẹle Erelu Bisi
Fayẹmi lọ ni aṣoju orileede Naijiria lọ silẹ Hungary, Dọkita Ẹniọla Ajayi;
igbakeji Gomina ipinlẹ naa tẹlẹ ri, Arabinrin Modupẹ Adelabu atawọn agbaagba obinrin
nipinlẹ naa.
No comments:
Post a Comment