IKU NI WỌN FI N WA TITI OSENI KAAKIRI BAYI O - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, February 13, 2019

IKU NI WỌN FI N WA TITI OSENI KAAKIRI BAYI O

Bọsun Ọlaniyi, Abẹokuta

Bi kii ba a ṣe pe ori to ko adije sipo Sẹnetọ labẹ ẹgbẹ oṣelu ADC, Ọnarebu Titi Oseni-Gomez ni, boya alẹ oni ni ko ba jade laye pẹlu bi wọn ṣe lawọn agbanipa n fibọn le kaakiri.


Agbegbe Adatan niluu Abẹokuta la gbọ pe Titi Oseni-Gomez to fẹ ẹ lọ ṣoju ẹkun Abẹokuta South nile igbimọ aṣofin agba niluu Abuja ninu idibo ọjọ Satide to n bọ yi la gbọ awọn agbanipa naa ti yinbọn fun ninu mọto ẹ.

Bo tilẹ jẹ pe a ko tii ri ẹkunrẹrẹ bi nnkan naa ṣe ṣẹlẹ, ṣugbọn a gbọ pe asiko to lọọ sabẹwo abẹle s'awọn eeyan fun igbaradi idibo to n bọ lọna yi la gbọ pe wọn tọpinpin ẹ de bẹ.

Lara awọn amugbalẹgbẹ obinrin to ti figba kan ri jẹ abẹnugan ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ogun, iyẹn lasiko ijọba Ọtunba Gbenga Daniel, Ọgbẹni Dejie Rowlands to fiṣẹlẹ naa to wa leti so pe gbogbo gilaasi mọto Titi Oseni-Gomez ni wọn fibọn fọ danu.

Wọn ni ṣe lobinrin naa sare bẹrẹ mọlẹ ninu mọto to wa, ki ọta ibọn naa ma baa ba.

Titi Oseni-Gomez ni obinrin to tun lorukọ daadaa nidi oṣelu, to si ṣee ṣe ko yege nibi idibo to n bọ naa lati fẹyin Gomina Amosun gbolẹ.

AWIKONKO gbọ pe, bi wọn ṣe n f'iku wa obinrin naa kaakiri lasiko yi, ọ lọwọ oṣelu ninu.

Lati fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, AWIKONKO gbiyanju lati ba alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun sọrọ lori foonu, ṣugbọn titi dasiko ta a sakojọpọ iroyin yi tan la ko rii ba sọrọ, tori pe ẹrọ ibanisọrọ rẹ ko lọ.

Ṣugbọn sibẹ, adura AWIKONKO ni pe ki Ọlọrun tubọ maa fi isọ rẹ sọ obinrin naa, ati paapaa awọn oloṣelu to ku kuro lọwọ awọn onise ibi, agbanipa at'awọn afoju-fẹni.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI