NITORI ẸSUN AGBERE: MARY, ỌMỌDUN MỌKADINLOGUN GUN ỌKỌ Ẹ PA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, February 18, 2019

NITORI ẸSUN AGBERE: MARY, ỌMỌDUN MỌKADINLOGUN GUN ỌKỌ Ẹ PA

Kayeefi lọrọ ọdọmọbinrin ẹni ọdun mọkandinlogun kan, Mary Adeniyi ṣi jẹ fun ọpọ awọn to gbọ nipa iṣẹlẹ naa, to si mu ki wọn maa gbe e ṣepe nla-nla loriṣiriṣi.

Ọsan ọjọ Fraide to kọja yi niṣẹlẹ naa waye niluu Eko, iyẹn lagbegbe Ikorodu, loju ọna Ṣagamu nigba ti wọn sọ pe ọkọ Mary, Solomon Nduka, ẹni ọgbọn ọdun n fẹsun kan Mary pe o n ṣe agbere.

AWIKONKO gbọ pe kii ṣe akọkọ re e ti Solomon yoo maa fẹsun kan Mary pe o n yan oun jẹ, ati pe oun ko nii gba fun lati jẹ ko koba oun, idi ni yi ti wọn lawọn mejeeji fi maa wọya ija.

Lọjọ tiṣẹlẹ buruku naa maa ṣẹlẹ, a gbọ pe ṣe lawọn mejeeji tun wọya ija, ko too di pe Mary ti wọn lo n tọmọ oṣu mẹrin lọwọ fi ọbẹ gun Solomon lọrun pa.

Awọn ara adugbo lo wọ Mary de teṣan ọlọpaa nibi to wa bayii.


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI