AISAN BABA SUWE TUN GBỌNA MIN IN YỌ, OWO NLA LO NILO BAYII - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, February 16, 2019

AISAN BABA SUWE TUN GBỌNA MIN IN YỌ, OWO NLA LO NILO BAYII

Bọsun Ọlaniyi, Abeokuta

Ki alaafia to peye le jẹ ti gbajumọ oṣere tiata nni, Alaaji Babatunde Omidina, ẹni tawọn eeyan tun mọ si Baba Suwe, wọn ti sọ pe yoo dara ti awọn ọmọ Naijiria ba le dide iranlọwọ owo fun un, paapaa awọn gbajumọ nla-nla nidii oṣelu atawọn mi-in.

Ninu awọn oṣere tiata ti wọn maa n ṣapọnle awọn eeyan daadaa ninu iṣẹ tiata, o fẹ ẹ jẹ pe Baba Suwe nikan ni. Ọkunrin yii gan-an la fẹ ẹ le sọ pe oun lo sọ awọn oṣere tiata di ẹni to maa n ki awọn eeyan ninu sinima bii igba ti Wasiu Ayinde ba n ṣapọnle eeyan lasiko to ba n kọrin fuji lọwọ ni.

Fun ọpọlọpọ eeyan to ba ti lanfaani lati wo sinima Baba Suwe, bi ọkunrin alawada yii ba ṣe n darukọ oloṣelu kan, bẹẹ ni yoo maa darukọ awọn gbajumọ nla-nla paapaa awọn to n gbe niluu Oyinbo, ti yoo si maa ṣapejuwe iru eeyan ti wọn jẹ, ati bi awọn ṣe sunmọ ara to.

Ọkan pataki ninu awọn eeyan ti Baba Suwe maa n polongo ẹ ju ninu sinima ni Gomina ipinlẹ Eko tẹlẹ, Aṣiwaju Bọla Tinubu, o fẹẹ ma si sinima ẹ kan bayii ti Babatunde Omidina ko ti ni polongo Tinubu. Bi o ba ṣe n sọ nipa eeyan rere ti ọkunrin oloṣelu yii n ṣe, bẹẹ naa ni yoo maa jẹ ki gbogbo eeyan mọ wi pe, ajọṣepọ nla wa laarin awọn, ati pe ẹni ti oun ko le fi ṣere ni, ti tọhun naa ko le fọrọ oun ṣere.

Bi Baba Suwe ṣe n ṣe yii, bẹẹ gẹgẹ naa lo ṣe lasiko igba ti Babatunde Raji Faṣọla naa fi wa lori ipo.

Ni bayii ti ọkunrin oṣere alawada nla yii wa ninu idaamu, ohun tawọn eeyan n sọ ni pe, yoo dara ti awọn oloṣelu yii ba le lo ipo wọn lati ran an lọwọ, paapaa nipa itọju ẹ, ti alaafia yoo fi to o lara, ti yoo si tun pada sidii iṣẹ sinima ẹ bii tẹlẹ.

Wọn ni, ipo ti Baba Suwe wa lasiko yii ko daa rara, ati pe niṣe ni ọkunrin naa de ara ẹ mọle, ti ki i fẹ jade sita mọ, nitori itiju.

Bi awọn eeyan kan ṣe n ke si awọn oloṣelu, paapaa Aṣiwaju Bọla Tinubu ati Babatunde Raji Fashọla, bẹẹ lawọn kan naa sọ pe, itiju nla lo maa jẹ fun ẹgbẹ awọn oṣere, ti wọn ko ba le dide iranlọwọ si ọkunrin alawada yii.

Wọn ni ohun to yẹ ki o jẹ ẹgbẹ naa logun ni bi wọn yoo ṣe gba ẹmi ẹni to ba n ṣaisan ninu wọn la, dipo ṣiṣe aisun aṣalẹ oṣere, eyi ti wọn n pe ni (Artist Candle night) fun eyikeyi to ba ku lojiji ninu wọn.

Ọkunrin kan ti a ba sọrọ lagbegbe Ikorodu sọ pe, “Nibi ti aye la ju de loni-in, ko yẹ ki igbe aye awọn oṣere maa ri bo ṣe n ri yii. Yatọ fun pe wọn n polongo iranlọwọ fun eyi to ba ni iṣoro ninu wọn, awọn funra wọn gan-an yẹ ki wọn ni eto pataki, bii eto adoju-tofo, ti yoo wa fun iranwọ ẹnikẹni ninu wọn to ba ku diẹ kaato fun.

“Bakan naa ni wọn gbọdọ fi ifẹ maa ba ara wọn lo, ko yẹ ko jẹ pe lasiko igba ti irawọ ọkan ninu wọn ba n tan ni wọn a maa polongo ẹ. O tun ṣe patak ki ẹni ti irawọ ẹ ba n tan lọwọ naa ṣọra ṣe, ko ranti wi pe igba maa n yi o, ki Ọlọrun ṣaanu Baba Suwe, ki alaafia to peye le to o lara.”

Tẹ o ba gbagbe, o ṣe diẹ ti awuyewuye aisan to n ṣe Baba Suwe yii ti wa nita, ṣugbọn ohun kan to maa n ya ọpọ lẹnu ni pe, ni kete ti iroyin ba ti gbe e wi pe ọkunrin alawada yii n ṣaisan, loju-ẹsẹ loun naa a ti sare bọ sita ta a sọ pe ko si ohun kan bayii to n ṣe oun.

Ṣa o, awọn ti wọn sunmọ ọn, ti wọn lanfaani lati ri i sọ pe, ninu inira lo wa, ati pe aisan n se e gidigidi, bẹẹ lo nilo iranlọwọ gbogbo ọmọ Naijiria ki ara ẹ le ya, ko le raaye jeere gbogbo wahala to ti ṣe laaarọ ọjọ ẹ nidii iṣẹ tiata.

- Magasinni Alore

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI