Ile ẹjọ giga kan to fikaleẹ
siluu Eko ti paṣẹ pe kawọn ọlọpaa lọọ gbe Balogun ẹgbẹ agbabọọlu Super Eagles
tẹlẹ, Austin Okocha ti wọn tun n pe ni Jay Jay Okocha.
Ko si nnkan meji to mu ki adajọ
ile ẹjọ naa, Onidajọ Adebayọ Akintoye paṣẹ naa bi ko ṣe ti gbese owo ori ti wọn
ni Okocha jẹ, to si kọ lati san an, ko too di pewọn pe e l’ẹjọ, ṣugbọn ti ko
yọju si kọọtu latigba naa, iyẹn lọdun 2017.
Ẹsun mẹta ọtọọtọ ni wọn fi kan
Okocha lọjọ kẹfa, oṣe kẹfa ọdun 2017 to nii ṣe pẹlu aisan owo ori fun ijọba
ipinlẹ Eko, eyi ti wọn loo tako ofin ipinlẹ naa ti oju iwe kẹrindinlọgọta,
abala A ati B (Section 56 (a) and (b)) tọdun 2006, pẹlu ofin pawo wọle ti
orileede yi, ti oju iwe kẹrinlelaadọrun abala kinni (Section 94(i)) tọdun 2004.
Agbẹjọro to fẹsun naa kan
Okocha, Y.A Pitan sọ pe fun igba akọkọ ti ẹjọ naa yoo waye lọjọ karun oṣu kẹwa
ọdun 2017, o ṣeni laanu pe ọkunrin agbabọọlu naa ko yọju, to si jẹ pe awọn ti
fun un niwe adajọ pe ko yọju si kọọtu.
O ni gbogbo igba ti wọn fi n pe
ẹjọ naa, ko sigba kan ri ti Okocha fi yọju si kọọtu titi di ọjọ kọkandinlogun
oṣu keji ọdun yi, iyẹn ọjọ Tuside to kọja yi, o wa a rọ adajọ naa pe ko fun
awọn laṣẹ lati lọọ fi ọlọpaa gbe Okocha nibi kibi to ba wa.
Onidajọ naa, Akintoye wa a sun
igbẹjọ min in siwaju di ọjọ kẹẹdogun oṣu kẹrin ọdun yi pẹlu aṣẹ pe ki wọn fi
ọlọpaa gbe ọkunrin naa wa.
No comments:
Post a Comment