Folukẹ Aduragbemi, Ọṣun
Ko si orin meji ti Gomina ana nipinlẹ Ekiti, Peter Ayọdele Fayọsẹ n kọ bayii bi ko ṣe orin ‘Ile lapoti n jokoo dedi’ latari bi ajọ to n gbogun ti iwa jẹgujẹra, iyẹn EFCC ṣe sọ pe awọn yoo ji de ile ẹ lati beere owo Atiku lọwọ ẹ.
Ori ẹka ayelujara Twitter ni
Fayọṣe ti gbe ọrọ naa sita ni alẹ ana pe oun ti ṣetan fun ajọ EFCC, ko sibi kan
toun n salọ.
Fayoṣe ni oun gbọ pe awọn oṣiṣẹ
ajọ to n gbogun ti iwa ajẹbaanu ati iṣowo ilu kumọkumọ EFCC yi ti de siluu
Ekiti lati yabo ile oun to wa ni Afao-Ekiti laarọ ọjọ oni tii ṣe Fraide.
Fayọṣe ni oun gbọ pe owo ti
oludije sipo Aarẹ labẹ ẹgbẹ oṣelu PDP, Alaaji Atiku Abubakar fi n ṣe ipolongo
ni wọn n wa bọ lọdọ oun, toun si ti mura silẹ de wọn.
Gomina ana nipinlẹ Ekiti yi tun
ṣalaye loju opo Twitter rẹ pe ko si ẹni to le dunkoko mọ awọn eeyan ipinlẹ
Ekiti nitori pe ẹni ti ko ba jẹ gbi, ko le ku gbi.
Fayoṣe ni ifẹ awọn ọmọ ipinlẹ
Ekiti ni yoo wa si imuṣẹ ni igbẹyin-gbẹyin.
Bẹẹ lo ni awọn kan ti gba idajọ
wọn, bẹẹ ni ti awọm miran ṣi n bọ lọna laipẹ.
O wa a fikun ọrọ ẹ pe gbogbo rẹ
yoo dopin lọjọ Abamẹta lẹyin ti idibo Aarẹ ati tawọn aṣofin agba ba waye tan.
No comments:
Post a Comment