Folukẹ
Aduragbemi, Ọṣun
Aarẹ Muhammadu Buhari ti gbe oṣuba kare fun gbogbo ọba patapata nipinlẹ
Ekiti lori bi wọn ṣe gbaruku ti gomina ipinlẹ naa, Dọkita Kayọde Fayẹmi ninu
idibo to waye lọdun to kọja.
Lonii ọjọ Tusde ni Aarẹ Buhari dupẹ lọwọ awọn ọba naa lasiko to ṣe
ipolongo idibo lọ sipinlẹ naa, nibẹ lo ti ran wọn leti bo ṣe bawọn ṣepade ni
nnkan bi ọjọ meloo kan s’ọjọ idibo.
Aare Buhari ni
iyalẹnu lo jẹ foun pẹlu esi idibo naa, ati paapaa awọn akanṣe iṣẹ to ti gbe ṣe
laarin igba to fi di gomina, nitori pe iru awọn nnkan ti Gomina Fayẹmi ti n ṣe
ko tii ṣẹlẹ ri nipinlẹ naa.
O wa a tun rọ
gbogbo awọn Ọba naa, atawọn araalu pe iru aduroti ti wọn fun Gomina Fayẹmi
lasiko idibo gomina wọn to kọja ni ki wọn foun naa lasiko idibo to wọle de yi,
o ni ki onikaluku wọn jade lati dibo lọjọ naa.
Nigba toun naa n
sọrọ Gomina Fayẹmi ni ijọba APC kaakiri orileede yi ni wọn ni agbekalẹ lati maa
mu awọn eeyan siwaju, nitori pe awọn araalu lo jẹ wọn logun, nitori ẹ lawọn ṣe
gbọdọ maa fi wọn sipo akọkọ.
O ni lati bii oṣu
mẹta sẹyin to ti wọle lawọn araalu ti n jẹ mudun-mudun eto oṣelu awaarawa,
nitori pe owo oṣu awọn oṣiṣẹ lo n lọ deede laisi idaduro. O wa a gbawọn eeyan
lamọnran pe ki wọn dibo yan Aarẹ Buhari lẹẹkeji.
No comments:
Post a Comment