NITORI IDIBO GOMINA, ṢỌỌṢI MFM SUN IPADE ADURA OLOṢOOṢU WỌN SIWAJU - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, February 2, 2019

NITORI IDIBO GOMINA, ṢỌỌṢI MFM SUN IPADE ADURA OLOṢOOṢU WỌN SIWAJU

Folukẹ Aduragbemi, Ọṣun
 Oludasilẹ ṣọọṣi Ori Oke Ina ati Iṣẹ Iyanu (Mountain of Fire and Miracles Ministries), MFM, Dọkita Daniel Kọlawole Olukọya ti kede sita gbangba pe ipade adura oloṣooṣu wọn, iyẹn Agbara Gbọdọ Paarọ Ọwọ (Power Must Change Hands), eyi to maa waye ni gbogbo ọjọ Satide Abamẹta akọkọ ninu oṣu ko nii lọ bo ṣe maa n lọ loṣu kẹta to n bọ.

Kii ṣe pe eto adura naa ko nii waye ninu oṣu kẹta rara, ṣugbọn Satide Abamẹta keji ninu oṣu kẹta ni ipade adura naa yoo waye.

Dọkita D. K Olukọya lo kede ọrọ naa sita nibi ipade adura ti oṣu keji, eyi to waye lonii, ọjọ keji oṣu keji ọdun 2019.

Ko si nnkan meji to fa a ti wọn fi sun ipade naa siwaju di, ọjọ kẹsan an oṣu kẹta tii ṣe Satide keji ninu oṣu kẹta.

Fawọn to ba mọ bi eto oṣelu orileede yi ṣe n lọ si, wọn a mọ pe Satide akọkọ ninu oṣu kẹta ni eto idibo awọn gomina kaakiri orileede Naijiria yoo waye, t'awọn eeyan yoo si lọ dibo lọjọ naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI