Ikọ̀
Chelsea má tún ríyà àìdéléwí ẹlẹ́kejì he láàárín ọ̀ṣẹ̀ méjì nínú ìdíje ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì,
Premier League lónìí yìí pẹ̀lú bí Ikọ̀ Mancity ṣe dín dùndún ìyà fún wọn.
Àmì
ayò mẹ́fà ni Ikọ̀ Mancity fi kọ́ Chelsea lẹ́kọ̀ọ́ èyí tí ó sì ti mú wọn wà ní
orí tábílì ìdíje náà.
Ìyà
yìí ló jẹ́ ẹlẹ́ẹ̀kejì irú rẹ̀ tí Ikọ̀ Chelsea yòó jẹ lókè ìta lẹ́yìn èyí àmì
àyò mẹ́rin tí Bournemouth fi jẹ wọ́n.
Raheem
Sterling ló kọ́kọ́ síde góòlù fún Mancity ní ìṣẹ́jú mẹ́rin tí ìfẹṣẹ̀wọnṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀
kí IIkay Gundogan àti Aguero tó sọ ọ́ di mẹ́rin ní abala àkọ́kọ́ ìfẹṣẹ̀wọnṣẹ̀
náà.
Golí-wòmí-n-gbáa
tí Aguero tún gbá wọlé ni Mancity fi bẹ̀rẹ̀ abala kejì ìyà náà fún Chelsea kí
Sterling tó fọba lé e.
Igbà
àkọ́kọ́ rèé tí Mancity yóò fi àmì ayò yìí bori Chelsea ńinú ìfẹṣẹ̀wọnṣẹ̀ tí wọ́n
ti gbá pẹ̀lú wọn tí Chelsea sì má ń borí wọn.
Pẹ̀lú
ìjáwé olúborí yìí, Aguero ti ní àkọsílẹ̀ hátíríkì mọ́kànlá nínú ìdíje yìí.
No comments:
Post a Comment