TINUBU FẸSUN KAN ỌBASANJỌ L'EKO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, February 10, 2019

TINUBU FẸSUN KAN ỌBASANJỌ L'EKO

Ibudo itọju aisan jẹjẹrẹ


Aarẹ Muhammadu buhari ti ṣi ibudo kan ni ile iwosan ijọba to wa ni Fasiti ilu Eko fun itọju aisan jẹjẹrẹ.

Iroyin sọ wi pe ibudo itoju ọhun yoo ni awọn irinṣẹ ti yoo le ṣeranwọ lati dena ati lati tete mọ bi eeyan ba ni aisan jẹjẹrẹ fun ilo ọpọlọpọ ọmọ Naijiria.

Eyi waye gẹgẹ bi ọkan lara alakalẹ eto fun ibẹwo aarẹ Buhari si ipinlẹ Eko lọjọ ẹti.

Asíwáju ẹgbẹ́ òṣèlú APC Bola Ahmed Tinubu ti rọ àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ Eko àti Nàijíríà lápapọ láti mú ìká ìlábẹ̀ wọn lọ sí ibi ìdìbò lọ́ja kẹrindínlógún osu yìí láti lọ dibo.

O sọ èyí di mímọ níbi ayẹyẹ ìpolongo ìdìbò ààrẹ tó wáyé ni pápá ìṣeré Teslim Balogun to wa ní Surulere ní ìpínẹ̀ Eko lonii ọjọ sátide, ó ni ìka àwọn ènìyàn ni àgbára wọn láti dibò fún ẹni to bá wù wọn.

Tinubu fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé káàdì ìdìbò wọn pẹlú ṣe pàtàkì jùlọ ki wọn si lo gbogbo ọ̀nà ti wọn ba mọ láti dààbò bòó, bákan náà ni ó ṣe pàtàkì kí wọn tú jáde lọ́jọ́ ìdìbò.

Lásikò yìí kan náà ni Tinubu fi ẹsun kàn pé ààrẹ Olusegun Obasanjọ ni ó ṣe magomago ìbò jùlọ ní orilẹ̀-èdè yìí, pàápàá jùlọ lóri ọ̀rs to ni Ya'adua sọ lóri ìdìbò tó gbé oun wọlé lọdun 2007

Tinubu tun fi ẹsun kan Obasanjọ pé ohun lo lé ọ̀pọ̀ àwọn ilé iṣẹ́ ǹlá-ńla lọ kúrò lórilẹ̀-èdè yìí lásìkò ìjọba rẹ̀.

Bótilẹ̀ jẹ pé titi di àsìkò ti ìròyìn yìí fi n jáde ààrẹ Obasanjọ kò tii fèsì lóri ẹsun ti Tinubu fi kàn-án yìí.

- BBC

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI