O TAN O; WỌN TI FI OṢELU HAN ỌLAMIJU, ỌMỌ ALAO AKALA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, February 21, 2019

O TAN O; WỌN TI FI OṢELU HAN ỌLAMIJU, ỌMỌ ALAO AKALA

Bello Abass n gba iwe ẹri lọwọ Kọmiṣọna fun ijọba ibilẹ ati oye jijẹ nipinlẹ Ọyọ, Bimbọ Kọlade
...wọn bura fun igbakeji ẹ gẹgẹ bi alaga ijọba ibilẹ

Lẹyin ti wọn yọ Ọlamiju Alao Akala, to jẹ ọmọ gomina ana nipinlẹ Ọyọ kuro nipo gẹgẹ bii alaga ijọba ibilẹ ariwa Ogbomoṣọ, iyẹn Ogbomoso Noirth, ijọba ipinlẹ Ọyọ ti ṣebura fun igbakeji rẹ, Abass Bello Bayewuwọn gẹgẹ bii alaga ijọba ibilẹ naa.

Kọmiṣọna fun amojuto ijọba ibilẹ ati oye jijẹ, Bimbọ Kọlade lo ṣeto ibura naa nileeṣẹ ijọba ibilẹ Ogbomọṣọ North.

N ṣe ni awọn agbofinro pọ babi si ayika ileeṣẹ ijọba ibilẹ naa, gẹgẹ bii awọn tisẹlẹ naa ṣoju wọn ṣe sọ.

Laipẹ yii ni awọn kansilọ mẹrin ninu mẹwa to wa ni ijọba ibilẹ naa, dibo yọ Ọlamiju lẹyin to kede pe oun n fi ẹgbẹ oṣelu APC silẹ lọ si ẹgbẹ oṣelu ADP, nibi ti baba rẹ ti n gbe igba dije fun ipo gomina ipinlẹ Ọyọ.

Ni owurọ ọjọru ni gomina tẹlẹ nipinlẹ Ọyọ, Adebayọ Alao Akala ṣi n fi to ileeṣẹ BBC news Yoruba leti pe, iwa kotọ ti ko lee duro niwaju ofin ni yiyọ ti wọn yọ ọmọ oun nipo ati pe, oun ṣi ni alaga ijọba ibilẹ Ogbomọṣọ North.

- BBC

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI