NITORI IBO SATIDE: GOMINA AMOSUN LOUN YOO PIN BILIỌNU KAN NAIRA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, February 21, 2019

NITORI IBO SATIDE: GOMINA AMOSUN LOUN YOO PIN BILIỌNU KAN NAIRA

Bọsun Ọlaniyi, Abeokuta 

Bo tilẹ jẹ pe ko tii sẹni to gba ọrọ gomina ipinlẹ Ogun, Ibikunle Amosun gbọ nigba to sọ pe oun yoo pin owo ti ko din ni bilọnu kan naira fawọn tijọpa ipinlẹ Ogun wo ile wọn lasiko ti wọn n fẹ gbogbo opopona ipinlẹ naa, ṣugbọn nnkan to tun jẹ ki wọn fẹẹ gbagbọ diẹ ni pe ojoojumọ ni Gomina Amosun n pin owo fawọn araalu, ki wọn le dibo yan an fun ipo Sẹnetọ to tun n du.

Gomina Amosun lo sọrọ naa lonii lasiko to n ṣabewo sawọn agbegbe kọọkan ti aknṣe iṣẹ ti n lọ lọwọ, o ni oun yoo gbe biliọnu kan naira silẹ fawọn ti wọn padanu ile wọn latari bi titi ṣe jẹ ile wọn.

Gomina Amosun sọ pe miliọnu mẹsan an ataabọ (9.5B) naira loun ti fawọn ti titi jẹ ile wọn kaakiri ipinlẹ Ogun gẹgẹ bi owo gba ma binu ninu miliọnu mọkanla (11B) naira tijọba ya sọtọ fawọn eeyan naa.
O ni boun ba gbe biliọnu kan naira naa silẹ, gbogbo owo toun gbe silẹ yoo jẹ bilọnu mẹwaa ataabọ naira, ti owo naa yoo si ku ẹẹdẹgbẹta miliọnu naira lati le jẹ kowo naa pe, toun yoo si ko o silẹ koun too kuro nipo.

Amosun ni lootọ, awọn eeyan oun lawọn ti titi jẹ ile wọn , toun ko si gbọdọ fi ẹtọ wọn dun wọn. O loun ṣeleri pe gbogbo nnkan to ba jẹ ẹtọ wọn loun yoo ko silẹ kijọba oun too palẹmọ ẹru ẹ.

Bakan naa lo tun fidi ẹ mulẹ pe oun ko tun ni i gbagbe awọn ara agbegbe Ilogbo-Iju ati Adigbe si Onikolobo, nitori pe gbogbo wọn nijọba yoo gbọ bukata wọn, ati pe kawọn ti wọn gbawe emi ni mi nilẹ (Home Onwers) lọọ fọkan ara wọn balẹ, nitori pe iwe wọn ti wa nilẹ.

Gbogbo awọn to gbọ ọrọ naa ni wọn n mi ori wọn pe igba wo ni Gomina Amosun fẹẹ jawọ ninu iro pipa, nitori pe lati bii ọdun mẹjọ to ti wa nibẹ, ko jawọ ninu irọ pipa, paapaa bo ṣe yi ọrọ ẹ pada pe ko si ijọba to le ṣe gbogbo iṣẹ tan lẹẹkan ṣoṣo.

Lara awọn to b’AWIKONKO sọrọ ta a forukọ bo laṣiri so fun wa pe awọn ko nigbagbọ mọ ninu gomina Amosun nitori pe ẹtanjẹ ti pọ ju ninu ọrọ ẹ, ati pe ko sẹni ti ko mọ pe ẹtanjẹ lasan lo wa ninu owo to n pin lasiko yi, ki wọn le ba a dibo fun.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI