ỌLỌPAA TI KO BA LO TAAGI LỌJỌ IDIBO YOO RU IGI OYIN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, February 14, 2019

ỌLỌPAA TI KO BA LO TAAGI LỌJỌ IDIBO YOO RU IGI OYIN

Mohammed-Adamu
Bọsun Ọlaniyi, Abeokuta

Ọga ọlọpaa patapata lorileede Naijiria, Mohammed Adamu ti fi ọrọ sita pe gbogbo oṣiṣẹ ọlọpaa ti ko ba lo taagi gẹgẹ bi aami idanimọ lasiko idibo to n bọ lọna lọjọ Satide Ọtunla yoo fẹnu fẹra bi abẹbẹ, nitori pe igi oyin lo ru.


Eyi lọ nibamu pẹlu ofin tuntun ti wọn ṣe fun eto idibo, lati le jẹ ki eto naa lọ nirọwọ irọsẹ, lai si wahala kankan.

O lawọn ọlọpaa ti wọn ba pin sawọn agbegbe ti idibo yoo ti waye ni wọn gbọdọ fi aami idanmọ, iyẹn taagi sọrun wọn lati le mọ awọn to ba jẹ ojulowo yatọ sawọn ayederu ọlọpaa.

Bakan naa lo tun jẹ ko di mimọ pe bo tilẹ jẹ pe awọn ọlọpaa ti yoo ṣiṣẹ lawọn agbegbe ti idibo yoo ti waye lọjọ naa, ṣugbọn sibẹ, wọn yoo lo irinṣẹ mamugaari, iyẹn handcuffs lọjọ naa.

Bẹẹ lo tun sọ pe gbogbo awọn ọlọpaa naa gbọdọ ti de awọn agbegbe ti wọn pin si laago marun aarọ ki eto too bẹrẹ rara, lati le fimu finlẹ daadaa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI