NITORI IJA KAṢAMU ATI ADEBUTU, ATIKU LOUN KO LỌ SIPINLẸ OGUN MỌ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, February 14, 2019

NITORI IJA KAṢAMU ATI ADEBUTU, ATIKU LOUN KO LỌ SIPINLẸ OGUN MỌ

Bọsun Ọlaniyi, Abeokuta 

Adije sipo Aarẹ orileede Naijiria labẹ ẹgbẹ oṣelu PDP, Alaaji Atiku Abubakar ti fagile ipolongo to yẹ ko ṣe wa siluu Abẹokuta tii ṣe olu-ilu ipinlẹ Ogun loni Tọside, ọjọ kẹrinla oṣu keji.

Iroyin to te AWIKONKO lọwọ jẹ ko ye wa pe ko si nnkan meji to mu ki wọn fagile ipolongo naa bi ko ṣe ti wahala to wa ninu ẹgbẹ nipinlẹ Ogun, iyẹn lori bi ẹgbẹ naa ṣe pin si meji.

Kii ṣe tuntun mọ pe orukọ Sẹnetọ Buruji Kaṣamu ni ajọ eleto idibo, INEC fi orukọ rẹ sita gẹgẹ bi adije sipo gomina fun ẹgbẹ oṣelu naa nibamu pẹlu aṣẹ ile ẹjọ to ga ju lọ.

Ati pe ojoojumọ lawọn mejeeji n gbe ara wọn lọ sile ẹjọ, paapaa bo ṣe jẹ Ọnọrebu Ladi Adebutu ni apa kan ninu awọn igbimọ amuṣẹ ṣe ẹgbẹ naa faramọ gẹgẹ bi adije, ṣugbọn ti ile ẹjọ sọ pe Kaṣamu nipo naa tọ si, to si mu ki ajọ INEC forukọ rẹ sita.

Ọgbẹni Bayọ Dayọ ni ile ẹjọ paṣẹ pe ko maa ṣakoso ẹgbẹ naa lọ nipinlẹ Ogun titi di oṣu kẹrin ọdun 2020, ṣugbọn ti Ọnọrebu Sikirulai Ogundele sọ pe ko le ri bẹẹ.

Ohun ta a gbọ ni pe latigba ti ajọ INEC ti fi orukọ Kaṣamu sita ni wahala naa tun ti bẹrẹ sii gbona jọjọ.

Idi ni yi ti Alaaji Atiku Abubakar ṣe sọ pe oun ko mọ ẹni toun yoo fa lọwọ soke gẹgẹ adije laarin Buruji Kaṣamu ati Ladi Adebutu.

Ọkan lara awọn igbimọ amuṣẹ ṣe ẹgbẹ naa, ẹni ta a forukọ bo laṣiri fidi rẹ mulẹ pe lati ma jẹ ki wahala to ṣẹlẹ laarin awọn ọmọ ẹyin Gomina Amosun ati ti Dapọ Abiọdun tun pada ṣẹlẹ sawọn naa lasiko ti Aarẹ Buhari gbe ipolongo wa lo jẹ kawọn fagile.

Ẹni naa sọ pe kawọn igun mejeeji ṣi maa ba eto ipolongo wọn lọ, ẹni ti ile ẹjọ ba si da lare laarin awọn mejeeji ni yoo gba ogo to ba ya.

Ọgbẹni Kọla Ọlọgbọndinyan to jẹ agbẹnuso fun ẹgbẹ oṣelu PDP fidi ẹ mulẹ pe lootọ lawọn ti fagile ipolongo wọn wa sipinlẹ Ogun, ati pe bawọn ṣe fagile tipinlẹ Ogun naa lawọn tun fagie eyi to yẹ ko waye niluu Abuja naa pẹluu.

Ọlọgbọndiyan sọ pe “Lootọ ni pe a ti fagile awọn ipolongo to yẹ ko waye nipinlẹ Ogun ati niluu Abuja. Idi ta a se fagile ni lati ma ṣe jẹ ki wahala ṣẹlẹ laarin awa ati atawọn alatako wa.”

Ninu iroyin min in lati gbọ pe Aarẹ Muhammadu Buhari naa tun ti fagile ipolongo ẹ niluu Abuja, eyi to yẹ ko waye lonii bakan naa, to si ti gbe e lọ siluu ẹ nipinlẹ Katsina.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI