Ọ̀YỌ́ 2019: MÀ Á GBA LAUTECH FÚN ÌPÍNLẸ̀ Ọ̀YỌ́ LÁÀÁRÍN ỌGỌ́RÙN-ÚN ỌJỌ́ ÀKỌ́KỌ́ BÍ MO BÁ DÓRÍ OYÈ – AKÁLÀ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, February 1, 2019

Ọ̀YỌ́ 2019: MÀ Á GBA LAUTECH FÚN ÌPÍNLẸ̀ Ọ̀YỌ́ LÁÀÁRÍN ỌGỌ́RÙN-ÚN ỌJỌ́ ÀKỌ́KỌ́ BÍ MO BÁ DÓRÍ OYÈ – AKÁLÀ

Àlàó Akálà

Adíje sí ipò gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú, African Democractic Party, ADP, Ọ̀túnba Àlàó Akálà ti fi dá àwọn ọmọ ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ lójú pé òun yóò gba Yunifásitì Ladoke Akintola sọ́wọ́ ìjọba ìpínlẹ̀ náà bí òun bá dé ipò gómìnà ìpínlẹ̀ náà.

Akálà ló ṣe ìlérí yìí ní ìlú Ìbàdàn níbi ìtàkùrọ̀sọ ìtagbangba fún àwọn adíje sípò gómìnà ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ èyí ti iléeṣẹ́ BBCNEWSYORÙBÁ gbé kalè, ọ́lọ́jọ́ Ẹtì.

Ó ní ìlérí yìí, èyí tí yóò di mímúṣẹ láàárín ọgọ́rùn-ún ọjọ́ àkọ́kọ́ rẹ̀ lórí oyè, ni ó jẹ́ ọ̀kan pàtàkì lára àwọn àfojúsùn òun lójúnà àtimú ìgbèrú àti ìdàgbàsókè bá ètò ẹ̀kọ́ ní ìpínlẹ̀ náà.

Ó tẹ̀síwájú nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé àjọpín ilé ẹ̀kọ́ náà pẹ̀lú ìpínlẹ̀ Ọ̀sun kò bùyì kún ìpínlẹ̀ náà rárá pàápàá bí ó ṣe jẹ́ pé ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ń sì ń pòǹgbẹ̀ fún yunifásitì àdàní tirẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àwọn ìpínlẹ̀ mìíràn ṣe ní tiwọn.

Ó ní àsìkò tó láti mú àyípadà rere bá ilé ẹ̀kọ́ gíga náà pẹ̀lú bí iṣẹ̀jọba òun yóò ṣe wá ìyánjú tó lọ́ọ̀rìn sí jíjẹ àwọn olùkọ́ ilé ẹ̀kọ́ náà ní owó oṣù pẹ̀lú ìdanilójú pé ètò ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ ni ìjọba òun yóò pèsè fún gbogbo akẹ́kọ̀ọ́ ilé-ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ àti girama ní ìpínlẹ̀ náà.


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI