ỌYỌ: AJỌ INEC F'ỌKAN AWỌN ARAALU BALẸ LORI IDIBO SATIDE - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, February 19, 2019

ỌYỌ: AJỌ INEC F'ỌKAN AWỌN ARAALU BALẸ LORI IDIBO SATIDE

Awọn olori ileeṣẹ agbofinro ati olori ajọ INEC ni ipinlẹ Ọyọ
Ọla Eyitayọ, Ọyọ 

Ajọ eleto idibo orilẹede yii, INEC ẹka ti ipinlẹ Ọyọ ṣe akanṣe apero pẹlu awọn aṣoju ẹgbẹ oṣelu ati awon agbofinro ti yoo kopa ninu eto idibo gbogbogbo ti yoo waye lọjọ Abamẹta.

Ipade naa to waye lonii, ọjọ Iṣẹgun ni olu ile iṣẹ ajọ eleto idibo ẹka ti ipinlẹ Ọyọ to fikalẹ silu Ibadan lo da lorii oniruuruu idahun si awọn ọkan-o-jọkan ibeere to ni i ṣe pẹlu idibo si ipo aarẹ ati ile igbimọ aṣofin ti yoo waye jakejado orilẹede yii lọjọ Abamẹta.

Ninu ọrọ rẹ nibi ipejọpọ naa, Kọmisana ajọ eleto idibo nipinlẹ Ọyọ, amofin Mutiu Agboke ṣe alaye wi pe gbogbo eto lo ti to lati rii daju pe eto idibo baa kẹsẹ jari.

O tẹsiwaju pe gbogbo kudiẹkudiẹ to ṣokunfa isunsiwaju ibo ni ijọba ti ṣe atunṣe rẹ bayii, bẹrẹ lati ori igba ibo ati awọn iwe to n ṣe akẹsilẹ esi ibo. O fi kun ọrọ rẹ pe omimi kan ko ni mi ibo ọjọ Abamẹta.

Kọmisọna tuntun fun ajọ ọlọpa nipinlẹ Ọyọ, Shina Tairu Olukolu naa ṣe afihan igbaradi ajọ ọlọpa nibi akanṣe apero naa. O ni ajọ naa ti n sa gbogbo ipa rẹ lati le jẹ ki ohun gbogbo lọ ni irọwọrọsẹ saaju, lasiko ati lẹhin ibo.

Komisọna ọlọpa fi kun ọrọ rẹ pe amojuto to pe ye yoo wa lori ayunlọ ati ayunbọ awọn ohun elo fun eto idibo naa.

Ẹgbẹ oṣelu kọọkan lo ni aṣoju nibi apero naa, gbogbo wọn sini wọn ni anfani lati beere ohun gbogbo to ru wọn loju nipa eto idibo ati ojuṣe awọn agbofinro.

Satide ọjọ kẹrindinlogun oṣu keji odun yii lo ti yẹ ki eto idibo naa waye ṣugbọn ajọ INEC sun eto naa siwaju nitori awọn kọkọrọ kan to ba eyin aja jẹ nipasẹ imurasilẹ ajọ naa.Nibayii, ọjọ kẹtalelogun oṣu keji ni eto idido naa yoo waye.

- BBC

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI