TÁÍWÒ ÒGÚNJỌBÍ TI DÁ GBÉRE FÁYÉ O, UCH LÓ KÚ SÍ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, February 11, 2019

TÁÍWÒ ÒGÚNJỌBÍ TI DÁ GBÉRE FÁYÉ O, UCH LÓ KÚ SÍ


Agbábọ́ọ̀lù fún Ikọ̀ 3SC ti ìlú Ìbàdàn nígbà kan rí, Táíwò Ògúnjọbí tí dá gbére fáyé pé ó dìgbóṣe.

Ògúnjọbí, ẹni tó tún ti fi ìgbà kan rí jẹ́ akọ̀wé àgbà fún àjọ tó ń darí aré bọ́ọ̀lù nílẹ̀ wa, NFF ló jásẹ̀ ní Ilé Ìwòsàn Ìkọ́ni, UCH ní ìlú Ìbàdàn lójó Ajé,

Gẹ́gẹ́ bí Awíkonko ṣe rí i gbọ́, ẹ̀yìn dídún àti ara ríro ni ogbóntarigì náà ń kígbé rẹ̀ èyí tó gbé e dé ilé ìwòsàn ọ̀ún láti ìlú Òsògbò kí ikú tó pa ojú rẹ dé.

Túndé Shamsudeen tó jé amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ ṣàlàyé pé ìròyìn ikú ọ̀gá rẹ̀ jẹ́ ohun iyàlẹ́nu fún òun nítorí àwọn jìjọ wà papọ̀ ní Ọjọ́bọ̀ ọ̀ṣẹ̀ tó kọ́ja kí olóògbé náà tó dágbére ìlú Ìbàdàn fún òun láti lọ ṣàyẹ̀wò ara rẹ̀.

Kí ọlọ́jọ́ tó dé, Ògújọbí ni alága àjọ tó ń darí aré bọ́ọ̀lù ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀sun.

 Ọmọ ọdún márùndínláàdọ́rin, 65 ni Ògúnjọbi tí ọlọ́jọ́ fi dé. Ó sì fi iyàwó àti ọmọ márùn-ún sílẹ̀ sáyé lọ.
  

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI