IRỌ́ NI O: LEAH SHARIBU Ò KÚ O – LAI MOHAMMED PARIWO SÍTA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, February 11, 2019

IRỌ́ NI O: LEAH SHARIBU Ò KÚ O – LAI MOHAMMED PARIWO SÍTA

Ìjọba àpapọ̀ ti ṣàpèjúwe ìròyìn pé ọ̀dọ́mọbìnrin tí àwọn ikọ̀ Boko Haram jí gbé ní Dapchi lọ́dún díẹ̀ sẹ́yìn, Leah Sharibu ti kú sí àhámọ́ gẹ́gẹ́ bí irọ́ funfun báláwú.

Mínísítà fún Ètò Ìròyìn àti Àṣà nílẹ̀ wa, Alhaji Lai Muhammed ló fi èyí síta nínú àtẹ̀jáde kan fún àwọn oníròyìn, nínú èyí tí ó pe ìròyìn náà ní irọ́ tó jìnà sí òótọ́.

Ó ní àhésọ lásán ni èyí tí àwọn ẹgbẹ́ alátakò gbẹ́ jáde láti ba ìjọba tó wà lóde lórúkọ jẹ́ pàápàá lásìkò tí ètò ìdìbò ń bọ́.

Ó ní ọ̀nà mìíràn rèé tí àwọn alátakò fẹ́ fi sọ Àarẹ Muhammadu Buhari lórúkọ burúkú kí àwọn ará ìlú lẹ̀ rí i gẹ́gẹ́ bí ẹni tí kò nání àláfíà àwọn ará ìlú tí ó sì dágunlá sí ìgbáyégbádùn wọn.

Ó wá rò àwọn ará ìlú láti gbè lẹ́yìn Àarẹ Buhari nítorí òun nìkan ni ọmọ oyè tí ó nífẹ̀ẹ́ ọmọ Nàíjíríà.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI