WỌN DA ẸJỌ IKU FUN DARAMỌLA ATI ADEDAYỌ L’ADO-EKITI - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, February 7, 2019

WỌN DA ẸJỌ IKU FUN DARAMỌLA ATI ADEDAYỌ L’ADO-EKITI

Folukẹ Aduragbemi, Ọṣun


Ile ẹjọ giga kan to fikalẹ siluu Ado-Ekiti ti paṣẹ pe ki wọn lọọ yẹgi fun ọrẹ mẹta kan, latari ẹsun ole jija ti won fi kan wọn, ati pe awọn ọrẹ meji naa la gbọ pe wọn ko niṣẹ meji ju ole jija lọ.

Oni Tọside ni Onidajọ John Adeyẹye gbe idajọ naa kalẹ fawọn ọrẹ meji yii, Oluwayọmi Adedayọ, ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn (27) ati Ṣeyi Daramọla toun jẹ ọmọdun mẹtalelogun

Onidajọ naa, Adeyẹye sọ pe ki i ṣe pe oun dee de da ẹjọ naa fun bi ko ṣe pe ko si awijare lori ẹsun ti wọn fi kan wọn naa, nitori pe ṣe ni wọn jẹbi patapata.

AWIKONKO gbọ pe ọdun 2016, iyẹn ọjọ kẹrin oṣu kẹjọ ni Daramọla ati Adedayọ ti jale naa nile igbafẹ kan ti wọn pe ni Club 15, Dynamic Lounge lagbegbe Irewumi, nitosi Bawa niluu Ado-Ekiti.

Awọn mejeeji la gbọ pe ọjọ kẹrindinlogun oṣu kẹwaa ọdun 2017 ni wọn foju wọn bale ẹjọ, ọjọ naa la si gbọ pe awọn mejeeji sọ pe lootọ lawọn jẹbi ẹsun meji ọtọọtọ ti wọn fi kan wọn.

A gbọ pe ibọn lawọn mejeeji mu lọọ fi pawọn eeyan lẹkun lọjọ naa, ti wọn si gba ẹrọ kọmputa ati foonu oriṣiriṣi nibẹ. Nigba taṣiri wọn maa tu, wọn nibi ti wọn ti n gbiyanju lati ta awọn nnkan ti wọn ji naa lọwọ ti tẹ wọn nigba ti wọn sọ pe wọn ko mọ bi wọn ṣe le ṣi awọn nnkan naa fawọn ti wọn fẹẹ ta wọn fun.No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI