ỌKỌ MI TI MU ORUKỌ MI LỌ SILE BABALAWO, Ẹ GBA MI O - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, February 7, 2019

ỌKỌ MI TI MU ORUKỌ MI LỌ SILE BABALAWO, Ẹ GBA MI O

Folukẹ Aduragbemi, Ọṣun
Iyaale ile ẹni ọdun marundinlogoji kan, Bukọla Ilesanmi lo wọ ọkọ ẹ, Kayọde Ilesanmi gbuurugbu lọ siwaju ile ẹjọ kọkọ-kọkọ to wa niluu Ado-Ekiti lonii Tọside, nibi to ti fẹsun oriṣiriṣi kan an pe ko jẹ koun gbadun igbeyawo ọlọdun mẹrindinlogun to wa laarin wọn.

Bukọla sọ pe ojoojumọ ni Kayọde kii foun lọkan balẹ, to tun ma n lu oun nilukulu bo ṣe wun un, ati pe kii tọju awọn ọmọ to pa wọn pọ, iya lo fi n jẹ wọn.

Obinrin naa to ni ojule kẹsan an, agbegbe Oke-Urẹjẹ, lopopona Poly loun n gbe sọ pe igba kan wa ti ọkọ oun pe oun ni ajẹ, to si bẹrẹ sii fi ada le oun kaakiri adugbo, to jẹ pe awọn eeyan lo gba oun lọwọ ẹ.

“Mo ranti ti mama ti sọ pe ki n kọ ọ silẹ nitori pe Kayọde n ṣe oogun, to si tun maa n mu oriṣiriṣi oogun wa sinu ile, tawọn ko si le sọrọ, nitori pe lilu lo maa n fawọn ṣe, pẹlu awọn ọmọ. Pabambari ẹ ni pe o tun mu orukọ mi lọ sile babalawo lọjọ kan. Inu iwe pelebe kan ti mo ti ri ninu apo ẹ, igba ti mo yẹ ẹ wo, orukọ mi lo wa nibẹ.”

Kayọde nigba toun naa n sọrọ sọ pe irọ nla ni Bukọla n pa moun, nitori pe oun ko ya ile babalawo ri nigbesi aye oun.

Aarẹ ile ẹjọ naa, Arabinrin Ọlayinka Akọmọlede ti wa a sun igbẹjọ min in siwaju di ọjọ keje oṣu kẹta.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI