Irọ nla ni, ko ri bẹẹ - Wọle
Ọkẹ
Folukẹ Aduragbemi, Ọṣun
Aburo
mi ni Ṣiji Ọlamiju, ko le si wahala laarin wa lailai - Wọle Ọkẹ
Aṣofin to n ṣoju awọn eeyan
lagbegbe
Oriade/Ọbọkun nile igbimọ aṣofin apapọ orileede yii, Ọnarebu Oluwọle Ọkẹ ti sọ pe
ko si ootọ ninu ahesọ kan to n lọ kaakiri pe awọn alatilẹyin oun da wahala silẹ
lagbegbe yẹn laipẹ yii.
Ọkẹ, to
n sọrọ lori ẹsun kan ti oludije labẹ ẹgbẹ oṣelu APC lagbegbe naa, Dọkita Siji Ọlamiju fi kan an laipẹ yii pe o ko awọn nnkan ija oloro wọ
agbegbe ọhun pelu ifọwọsowọpọ DPO ọlọpaa nibẹ.
Ọnarebu
yii ni gẹgẹ bii Amofin ati Aṣofin, oun mọ ewu to wa ninu kiko ibọn kaakiri lai gba aṣẹ lọdọ awọn ọlọpaa, oun ko si ni aṣẹ (license) naa lọwọ rara lati ṣe iru nnkan
bẹẹ.
Nibi ikọlu to waye laipẹ yi |
Ọkẹ fi
kun ọrọ rẹ pe oun ko mọ DPO ti wọn n sọ yẹn ri rara nitori ko si idi
kankan toun fi le maa ṣe wọlewọde pẹlu ẹ. O ni ai tii mọ oṣelu ṣe daadaa lo fa wahala fun Ọlamiju.
O ni odu ni oun ninu oṣelu agbegbe Oriade/Ọbọkun, kii ṣe aimọ fun oloko, awọn nnkan meremere toun si ti ṣe fawọn araalu lo fa a ti awọn alatilẹyin oun ninu ẹgbẹ oselu APC gan an fi po ju ti inu ẹgbẹ PDP gan an lọ.
Gbogbo
nnkan yii ti Ọlamiju
ri lo sọ pe o fa a to fi n wa gbogbo ọna lati fa oun sinu wahala,
eleyi ti oun ko si le faaye rẹ silẹ
lailai nitori aburo lo jẹ fun
oun ni gbogbo ọna.
O waa rọ awọn alatilẹyin ẹ lati ma ṣe
faaye gba ẹnikẹni lati bi wọn ninu, ṣaaju, lasiko ati lẹyin idibo ọjọ kẹrindinlogun oṣu keji ọdun yii.
Bẹẹ lo rọ awọn ọmọ ẹgbẹ APC lati dẹkun iwa ipa nitori idibo.
#Agbala Iroyin
No comments:
Post a Comment