WỌN NI WỌLE ỌKẸ ATI DPO ỌLỌPAA N FI TỌỌGI DA IGBORO RU L’ỌṢUN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, February 2, 2019

WỌN NI WỌLE ỌKẸ ATI DPO ỌLỌPAA N FI TỌỌGI DA IGBORO RU L’ỌṢUN


Irọ nla ni, ko ri bẹẹ - Wọle Ọkẹ


Folukẹ Aduragbemi, Ọṣun

Aburo mi ni Ṣiji Ọlamiju, ko le si wahala laarin wa lailai - Wọle Ọkẹ

Aṣofin to n ṣoju awọn eeyan lagbegbe Oriade/Ọbọkun nile igbimọ aṣofin apapọ orileede yii, Ọnarebu Oluwọle Ọkẹ ti sọ pe ko si ootọ ninu ahesọ kan to n lọ kaakiri pe awọn alatilẹyin oun da wahala silẹ lagbegbe yẹn laipẹ yii.

Ọkẹ, to n sọrọ lori ẹsun kan ti oludije labẹ ẹgbẹ oṣelu APC lagbegbe naa, Dọkita Siji Ọlamiju fi kan an laipẹ yii pe o ko awọn nnkan ija oloro wọ agbegbe ọhun pelu ifọwọsowọpọ DPO ọlọpaa nibẹ.

Ọnarebu yii ni gẹgẹ bii Amofin ati Aṣofin, oun mọ ewu to wa ninu kiko ibọn kaakiri lai gba aṣẹ lọdọ awọn ọlọpaa, oun ko si ni aṣẹ (license) naa lọwọ rara lati ṣe iru nnkan bẹẹ.

Image may contain: 6 people, beard
Nibi ikọlu to waye laipẹ yi
O ni aburo oun ni Ọlamiju, oun ko si si nipinlẹ Ọṣun lasiko ti wahala ti wọn n sọ ọhun ṣẹlẹ, ati pe awọn ọmọ ẹgbẹ APC ti wọn jẹ alatilẹyin Ọlamiju ni wọn da wahala naa silẹ lẹyin ti Dọkita naa fun wọn ni owo ti ko tẹ wọn lọrun nigba to ṣabẹwo sọdọ wọn.

Ọkẹ fi kun ọrọ rẹ pe oun ko mọ DPO ti wọn n sọ yẹn ri rara nitori ko si idi kankan toun fi le maa ṣe wọlewọde pẹlu ẹ. O ni ai tii mọ oṣelu ṣe daadaa lo fa wahala fun Ọlamiju.

Image may contain: 1 person, car 
O ni odu ni oun ninu oṣelu agbegbe Oriade/Ọbọkun, kii ṣe aimọ fun oloko, awọn nnkan meremere toun si ti ṣe fawọn araalu lo fa a ti awọn alatilẹyin oun ninu ẹgbẹ oselu APC gan an fi po ju ti inu ẹgbẹ PDP gan an lọ.

Gbogbo nnkan yii ti Ọlamiju ri lo sọ pe o fa a to fi n wa gbogbo ọna lati fa oun sinu wahala, eleyi ti oun ko si le faaye rẹ silẹ lailai nitori aburo lo jẹ fun oun ni gbogbo ọna.

O waa rọ awọn alatilẹyin ẹ lati ma ṣe faaye gba ẹnikẹni lati bi wọn ninu, ṣaaju, lasiko ati lẹyin idibo ọjọ kẹrindinlogun oṣu keji ọdun yii.

Bẹẹ lo rọ awọn ọmọ ẹgbẹ APC lati dẹkun iwa ipa nitori idibo.

#Agbala Iroyin

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI