WỌN TI SỌ GBOGBO ỌJỌ KEJE NINU OṢU KEJI DI ỌJỌ IDARIJI ẸṢẸ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, February 7, 2019

WỌN TI SỌ GBOGBO ỌJỌ KEJE NINU OṢU KEJI DI ỌJỌ IDARIJI ẸṢẸ


Folukẹ Aduragbemi, Ọṣun 

Gomina ipinlẹ Plateau, Simon Lalong ti kede sita pe gbogbo ọjọ keji ninu oṣu keji lọdọọdun ni yoo maa jẹ ọjọ idariji ẹṣẹ, ati pe ọjọ naa yoo tun ni ọlude nipinlẹ naa.

Oni tii ṣe tọside ni Gomina Lalong sọrọ naa nibi ti wọn ti fi ọgba kan ti wọn pe ni Ọgba Alaafia ati Idariji, iyen Garden of Peace and Forgiveness lelẹ niluu Jos.

O sọ pe “Gẹgẹ bi gomina ipinlẹ yi, mo duro lorukọ awọn eeyan rere nipinlẹ Plataeu lati tọrọ idariji lọwọ gbogbo awọn ọmọde ti wọn ti padanu awọn obi wọn nitori aile ṣe deede wa.

“A bẹbẹ fun idariji awọn obi ti wọn padanu awọn ọmọ wọn ninu ajalu nla to fitan buruku balẹ gẹgẹ bi eeyan alaafia.

“A tọrọ idariji lọwọ gbogbo ọkunrin ti wọn padanu iyawo wọn nigba ti a kuro ninu eeyan rere sinu eeyan buruku. A tọrọ idariji lọwọ awọn obinrin ti wọn padanu ọkọ wọn latari iwa were ọwọ wa, eyi to gba idariji ju ka maa ranti lọ.

“Oni jẹ ọjọ irin ajo itan gẹgẹ bi awa eeyan ipinlẹ Plataeu. Nitori to jẹ gẹgẹ bi ọjọ idariji. ọjọ ti a ti ya sọtọ lati farahan ninu irin ajọ wa gẹgẹ bi eeyan, ti yoo si maa wa lọkan wa nipa awọn ajalu oriṣiriṣi to ti n kọlu wa nipinlẹ yi lati ọdun 2001."

Gomina Lalong wa a rawọ ẹbẹ sawọn ọmọ ipinlẹ naa lati tan ọrọ idariji naa kaakiri gbogbo ipinlẹ naa, ki alaafia le tubọ jọba.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI