AARẸ BUHARI ṢETAN LATI MU GBOGBO ILERI Ẹ ṢẸ - AISHA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, March 5, 2019

AARẸ BUHARI ṢETAN LATI MU GBOGBO ILERI Ẹ ṢẸ - AISHA

AISHA BUHARI
Iyawo Aarẹ Orilẹede Naijiria, Arabinrin Aisha Buhari ti ni ọkọ oun yoo lo saa keji yii lati mu gbogbo ileri to ṣe lasiko ipolongo idibo lorilẹede Naijiria wa si imuṣẹ.

Aisha Buhari lasiko to n gbalejo lati ṣayẹyẹ bi ọkọ rẹ ṣe jawe olubori sọ wi pe, Aarẹ yoo gbogun ti iwa ibajẹ, iṣẹ ti oṣi eleyii ti yoo mu opin ba alafo to wa laaarin awọn olowo ati awọn alaini ni awujọ.

Iyawo aarẹ naa dupẹ lọwọ awọn obinrin ati ọdọ fun atilẹyin wọn lasiko idibo naa.

Bakan naa ni aarẹ Muhammadu Buhari ti wọn ṣẹṣẹ yan fun saa keji naa sọ wi pe oun mọ ipa ribiribi ti awọn obinrin ati ọdọ ko lasiko idibo naa, nitori naa oun yoo yan awọn obinrin sipo lati ba oun ṣiṣẹ.

Amọ, Aarẹ Buhari ni awọn obinrin to ni iwa ọmọluwabi to si fẹran orilẹede Naijiria ni oun yoo yan sipo.

Aarẹ naa fikun ọrọ rẹ wi pe oun yoo pese ohun ọgbin fun awọn agbẹ aroko ni iye owo ti ko kan ni leegun ẹyin, ki o ba le mu iwuri ba awọn ọdọ lati mu iṣẹ agbẹ lokunkundun.

- BBC

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI