ỌYỌ: NITORI ṢEYI MAKINDE, LADOYE LOUN KO ṢE GOMINA MỌ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, March 5, 2019

ỌYỌ: NITORI ṢEYI MAKINDE, LADOYE LOUN KO ṢE GOMINA MỌ

Seyi Makinde Denies Meeting Ajimobi In Ireland
Ọla Eyitayọ, Ọyọ

Oludije sipo Gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu New Progressive Movement (NPM) nipinlẹ Ọyọ, colonel Feyiṣayọ Ladoye ti kese sita gbangba pe oun ko dije dupo naa mọ, ati pe oun yoo ṣagbatẹru adije sipo Gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP, Ọgbẹni Ṣeyi Makinde.

Colonel Ladoye, to fi apa kan tan mọ ilu Ogbomọṣọ naa sọ pe ko si nnkan meji to jẹ koun fa sẹyin lati sọ pe oun ko dupo naa mọ, bi ko ṣe pe lati fun oludije labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP naa ni anfaani lati de ipo naa, ati pe lati jẹ kawọn eeyan gbaruku ti rẹpẹtẹ.

Nigba to n gbawọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu NPM naa lamọnran pe ki wọn dibo fun ẹgbẹ oṣelu PDP lọjọ Satide Abamẹta to n bọ yi nitori pe bawọn ba yan Ṣeyi makinde sipo naa, yoo ṣe daadaa ju ẹgbẹ oṣelu APC to ti ja wọn kulẹ lọdun mẹjọ lọ.

O ni boun ko ba fipo naa silẹ fun Ṣeyi makinde, bi ẹni to kan fẹẹ ba ibo ọjọ naa jẹ fun ẹgbẹ PDP ni, ati pe ẹgbẹ APC yoo lanfaani lati rọwọ, ati pe Ṣeyi Makinde mọ ọna abayọ si iṣoro to n koju ileewe giga gbogboniṣe ti LAUTECH.

Nigba to n rawọ ẹbẹ sawọn ẹgbẹ oṣelu kekeeke to ku pe ki wọn ṣagbatẹru ẹgbẹ oṣelu PDP, o ni ilu Ogbomọṣọ nikan lawọn oludije naa n wo lati ri ibo to pọ ju nipinlẹ Ọyọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI