AṢIRI OLE TO N JI FOONU TU NI SAPẸLẸ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, March 4, 2019

AṢIRI OLE TO N JI FOONU TU NI SAPẸLẸ

Ọjọ manigbagbe lọjọ Satide ọsẹ to kọja yi jẹ fun ọdọmọkunrin kan ti ko niṣẹ meji ju ole jija lo, latari bọwọ ṣe tẹ ẹ, ti wọn si luu debi pe ẹmi fẹ ẹ jabọ lara ẹ.

Ohun ta a gbọ ni pe awọn gendebinrin meji kan ni wọn kuro ninu yara wọn bọ si baluwẹ lati wẹ, ki wọn si too pada wọle, gendekunrin naa ti ji foonu wọn ko salọ.

Kani kii ṣe pe wọn tete pariwo sita ni, bo ya ki ba ti salo gbe, kọwọ si ma pada tẹ ẹ. Bi wọn ṣe rii mu ni wọn bẹrẹ sii dana iya fun, to mu ko maa bẹbẹ pe ki wọn ma pa oun.

Agbegbe Sapẹlẹ nipinlẹ Delta niṣẹlẹ naa ti waye. Awọn araadugbo ti wọn wa nitosi ni wọn ba a bẹbẹ pe ki wọn lọọ fa a le awọn ọlọpaa lọwọ, ti wọn si ṣe bẹẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI