Ẹ WO AWỌN NNKAN IJA OLORO TI WỌN TUN KO WỌ NAIJIRIA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, March 4, 2019

Ẹ WO AWỌN NNKAN IJA OLORO TI WỌN TUN KO WỌ NAIJIRIA

Kani ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Benue sun oorun asunpara ni, boya awọn agbanipa taṣiri wọn tu lọjọ Fraide ọsẹ to kọja yi ko ba ti ri iṣẹ wọn ṣe daadaa.

Bo tilẹ jẹ pe awọn ọdaran naa raaye salọ mọ awọn ọlọpaa lọwọ, ṣugbọn sibẹ, ajọyọ nla lo jẹ pe baagi ṣaka nla kan ti wọn fi ko awọn nnkan ija oloro naa si l'awọn ọlọpaa ri gba silẹ.

Agbegbe ijọba ibilẹ Katsina-Ala nipinlẹ naa la gbọ pe aṣiri wọn ti tu lasiko t'awọn ọlọpaa n ṣiṣẹ wọn kaakiri ilu.

Baṣiri wọn ṣe tu lagbegbe Takum ni wọn lawọn ọdaran naa ti koju ibọn s'awọn ọlọpaa, ati pe nigba ti wọn rii pe agbara wọn ko fẹ ẹ ka mọ, ni wọn ba ba ẹsẹ wọn sọrọ.

Alukoro ọlọpaa ipinlẹ naa, Catherine Anene fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, oun lo si jẹ ka mọ pe oogun abẹnu gọngọ loriṣiriṣi, ibọn AK47 mẹjọ, ọbẹ, ọta ibọn loriṣiriṣi atawon min in ni wọn ri gba.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI