Ko din ni eeyan mẹfa ọtọọtọ la gbọ pe aarun iba LASSA ti dẹmi wọn legbodo lawọn ipinlẹ bii Ẹdo, Ondo, Bauchi, Nassarawa, Taraba ati Cross River.
Ajọ n ṣakoso ati igbogunti
aarun lorileede yi, National Centre for Disease Control lo fidi ọrọ naa mulẹ
lọjọ Fraide ana.
AWIKONKO gbọ pe laarin ọjọ
kinni si ọjọ kẹrinlelogun oṣu kinni ọdun yi, awọn ti ko din ni ẹgbẹrun kan ati
igba le diẹ (1,249) lawọn ti gbọ nipa ẹ lawọn ipinlẹ mọkanlelogun, to fi mọ
Abuja, to si jẹ pe irinwo din diẹ (381) lawọn fidi ẹ mulẹ.
O tun jẹ ko di mimọ pe laarin
ọjọ kejidinlogun si ọjọ kẹrinlelogun oṣu keji, ko din ni iṣẹlẹ mẹtalelogun
tawọn tun gbọ nipa lawọn ipinlẹ bii Ẹdo, Ondo, Bauchi, Nasarawa, Taraba, Gombe,
Kaduna ati Cross River to si jẹ pe awọn oṣiṣẹ eleto ilera mẹẹdogun ni wọn
kagbako aarun naa.
No comments:
Post a Comment