WỌN FẸẸ TUN IBO AARẸ DI LỌJỌ KẸSAN AN OṢU YI - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, March 2, 2019

WỌN FẸẸ TUN IBO AARẸ DI LỌJỌ KẸSAN AN OṢU YI

Ajọ eleto idibo lorilẹede Naijiria ti sọ ọ di mimọ pe afikun idibo Aarẹ yoo waye lọjọ Abamẹta ọsẹ to n bọ tii ṣe ọjọ kẹsan oṣu kẹta ta a wa yi.

INECAfikun idibo Aarẹ yoo waye lọjọ kan naa pẹlu idibo gomina ati tile igbimọ aṣofin ipinlẹ kaakiri orileede yi.

Ọga agba ajọ INEC to n ri sọrọ iroyin ati ilanilọyẹ awọn oludibo, Festus Okoye ṣalayẹ pe idibo Aarẹ naa yoo waye nibi gbogbo ti ajọ INEC ti wọgile ibo Aarẹ lọjọ Satide ọsẹ to kọ ja.
 
O fikun ọrọ rẹ pe igbesẹ naa waye nibi ipade awọn ọga INEC ti ipinlẹ kọọkan l'Abuja.

Ajọ INEC ko le ran awọn oṣisẹ rẹ lọ si awọn ibudo idibo kan nitori rukerudo to bẹ silẹ lawọn agbegbe ọhun.

- BBC

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI