IDIBO GOMINA: WỌN NI ỌKAN GNI KO BALẸ MỌ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, March 4, 2019

IDIBO GOMINA: WỌN NI ỌKAN GNI KO BALẸ MỌ

Bọsun Ọlaniyi, Abẹokuta

Bi iroyin to tẹ AWIKONKO lọwọ laipẹ yi ba fi le jẹ otitọ, a jẹ pe afaimọ ki oludije sipo Gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu ADC nipinlẹ Ogun, Ọmọba Gboyega Nasiru Isiaka ma pada sọ pe oun ko dije dupo naa mọ bi ko ba fi wọle idibo to n bọ lọna yi.

Ohun ta a gbọ ni pe latari idibo apapọ orileede Naijiria to waye lopin ọsẹ to kọja lọ yi, nibi ti ẹgbẹ oṣelu ADC ti padanu kọja afẹnusọ lo mu ki Gboyega Isiaka maa binu sọrọ lasiko yi pe ko daju mọ pe oun yoo bori lakoko idibo.

Fawọn to ba mọ bi idibo to kọja yi ṣe lọ nipinlẹ Ogun, gbogbo adije sipo oṣelu labẹ asia ẹgbẹ naa, to fi mọ Ọnọrebu Titi Oseni-Gomez t'awọn eeyan ti n ro pe yoo jawe olubori ni wọn padanu patapata.

Ẹgbẹ oṣelu APC lawọn araalu dibo fun, ti diẹ lara awọn oludije labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APM si rọwọ mu diẹ.

Pẹlu bi nnkan se n lọ yi, ohun t'awọn eeyan n sọ ni pe ko daju pe ọkunrin naa yoo rọwọ mu ninu idibo to n bọ lọna yi.

Gẹgẹ bi ọkan lara awọn to sunmọ GNI to gbe ọrọ naa s'AWIKONKO leti ṣe sọ, o ni asiko ibinu ati iporuru ọkan ni ọkunrin naa wa bayii, ati pe inu ẹ ko dun mọ rara si esi ibo to kọja lọ naa ati eyi to n bọ lọna.

Ẹni naa to ni ka f'orukọ b'oun laṣiri jẹ ko ye wa pe nigba ti GNI n b'awọn oṣiṣẹ ẹ at'awọn amugbalẹgbẹ ẹ sọrọ laipẹ yi, o ni pẹlu ibinu lo fi sọrọ pe ṣe loun kan ri i pe owo ni wọn kan n gba lọwọ oun, wọn ko ṣiṣẹ owo naa.

O ni oun mọ pe pupọ ninu awọn to n tẹle oun lo jẹ pe tori owo lasan ni wọn ṣe n ki oun ni mẹsan an, mẹwaa, kii ṣe pe wọn n'ifẹ oun denu.

Bẹẹ ni wọn loo tun sọ pe oun ko nigbagbọ pe awọn eeyan yoo dibo foun lẹyin ọpọlọpọ owo toun ti na sita.

AWIKONKO gbọ pe igbagbọ GNI lasiko yi ni pe orin 'a o mu erin jọba, ẹwẹku ẹwẹlẹ' ni won kọ tẹle oun lẹyin, ati pe ọkan Akin lo fi n gbe e.

Bakan naa la tun gbọ pe pẹlu ibẹrubojo ni wọn fi n beere owo lọwọ ẹ bayii nitori pe wọn ko mọ iru ọrọ ti wọn yoo tun ba lẹnu ẹ bi wọn ba gbe ọrọ to nii ṣe pẹlu owo siwaju ẹ.

Fawọn to ba mọ Gboyega Isiaka daadaa, wọn mọ pe ẹlẹẹkẹta re e ti yoo maa gbe apoti dupo Gomina, akọkọ lo ba ẹgbẹ oṣelu PPN jade, ẹlẹẹkeji lo ba ẹgbẹ oṣelu PDP jade, to si jẹ pe ẹgbẹ oṣelu ADC lo n gba dupo bayii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI