IDIBO KU ỌJỌ MẸRIN, GOMINA AMOSUN DA ALAGA ẸGBẸ AWỌN OṢIṢẸ NIPINLẸ OGUN PADA SIPO, LẸYIN ỌDUN MEJI ATAABỌ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, March 5, 2019

IDIBO KU ỌJỌ MẸRIN, GOMINA AMOSUN DA ALAGA ẸGBẸ AWỌN OṢIṢẸ NIPINLẸ OGUN PADA SIPO, LẸYIN ỌDUN MEJI ATAABỌ

Bọsun Ọlaniyi, Abeokuta 

Gomina Ibikunle Amosun ti da alaga ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ nipinlẹ Ogun, Kọmreedi Akeem Ambali pada sipo lẹyin oṣu mejidinlọgbọn, iyẹn ọdun meji ati oṣu mẹrin to ti da a duro lẹnu iṣẹ.

Oni Tuside tii ṣe ọjọ karun-un oṣu kẹta ni olori awọn oṣiṣẹ patapata lorileede Naijiria, Kọmureedi Ayuba Wabba kede ọrọ naa sita fawọn oniroyin ni Oke-Mosan, Abẹokuta lẹyin ipade tawọn agbaagba ẹgbẹ awọn oṣiṣe naa ṣe pẹlu ijọba ipinlẹ Ogun.

Lọsẹ to kọja lọ lọhun, ni ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ kọ lẹta ranṣẹ si Gomina Amosun pe ko maa mura silẹ nitori pe awọn n bọ lati wa a ti ipinlẹ naa pa pẹlu iwọde ifẹhonuhan, ṣugbọn ti Gomina Amosun ni ki wọn ma dan an wo nitori pe ẹtẹ ni wọn yoo ba pade.

Bẹ o ba gbagbe, ọjọ kọkanlelọgbọn oṣu kẹwaa ọdun 2016 ni Gomina da alaga ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ nipinlẹ Ogun, Kọmreedi Akeem Ambali atawọn oṣiṣẹ mẹrinla min in latari ayẹyẹ ayajọ ọjọ awọn olukọ ti wọn ṣe lọdun naa, eyi ti wọn sọ pe o lodi sofin

Bo tilẹ jẹ pe awọn ti wọn da duro pẹlu Akeem Ambali ni Gomina Amosun dariji, to si ni ki wọn pada sẹnu iṣẹ wọn, ṣugbọn ti ko dariji Ambali, to si loun ko nii da a pada lailai.

Kọmureedi Ayuba Wabba sọ pe latari ipade tawọn ṣe pẹlu ijọba Gomina Amosun, awọn ti yanju gbogbo wahala to n ṣẹlẹ laarin awọn oṣiṣẹ ati ijọba, nitori naa, iwọde ifẹhonuhan ko nii waye mọ.

Bẹẹ lo tun sọ pe gbogbo nnkan to nii ṣe pẹlu awọn oṣiṣẹ ileewe giga Tai-Ṣolarin lawọn ti yanju.

Ẹkunrẹrẹ iroyin naa n bọ siwaju sii laipẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI