LẸYIN TI ALAO-AKALA GBA LATI ṢIṢẸ FUN APC, WỌN DA ỌLAMIJU PADA SIPO ALAGA IJỌBA IBILẸ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, March 2, 2019

LẸYIN TI ALAO-AKALA GBA LATI ṢIṢẸ FUN APC, WỌN DA ỌLAMIJU PADA SIPO ALAGA IJỌBA IBILẸ

Ọla Eyitayọ, Ọyọ 

Ko sẹni ti ko mọ bayii pe oṣelu agabangebe lo n lọ lọwọ lasiko yi, paapaa bawọn agbaagba lẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC ṣe n fowo ra awọn eeyan kaakiri lati ṣagbatẹru wọn, ki wọn le rọwọ mu ninu idibo awọn Gomina to n bọ lọna yi.


Ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress nipinlẹ Ọyọ ti kede sita pe awọn ti da Ọlamiju Akala pada sipo ẹ gẹgẹ bi alaga ijọba ibilẹ Ogbomọṣọ North.

Eyi waye lẹyin wakati diẹ ti baba ẹ, to jẹ oludije fun ipo gomina ipinlẹ Ọyọ ninu ẹgbẹ oṣelu Action Democratic Party, ADP, wọgile erongba rẹ, to si ni oun yoo ṣatilẹyin fun oludije ẹgbẹ oṣelu APC, iyẹn Adebayọ Adelabu.

Bo tilẹ jẹ pe Ọlamiju sọ pe dida ti wọn da oun pada ko ni nkankan ṣe pẹlu igbesẹ ti baba oun gbe, ṣugbọn ko sẹni ti ko mọ pe ọrọ oṣelu lasan ni, nitori pe oun ati baba ẹ jọ wa lọdọ Aṣiwaju Bọla Tinubu lọjọ Tọside ijẹta ni, nibi ti wọn ti ṣe paṣi-paarọ agbara.

Ọlamiju sọ pe 'wọn sọ pe awọn da oun pada lẹyin ti iwadi awọn fihan pe oun ko ṣẹ.'

Ọjọ Satide Abamẹta oni ni wọn da a pada sipo ẹ gẹgẹ bi alaga, ti yoo si bẹrẹ iṣẹ pada lọjọ Aje Mọnde ọsẹ to n bọ, iyẹn ọjọ kẹrin, oṣu kẹta ta a wa yi.

Ọjọ diẹ lẹyin ti Ọlamiju ṣatilẹyin gbangba fun baba rẹ to n dupo gomina ni wọn yọ ọ nipo, ti wọn si bura fun igbakeji rẹ gẹgẹ bi alaga tuntun.

O ṣalaye ninu ifọrọwanilẹnuwo to ṣe pẹlu BBC Yoruba pe wọn yọ oun kuro nipo nitori pe oun kuro lẹgbẹ APC lọ ọ darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu ADP lati ṣatilẹyin fun baba oun.

O si leri lati gbe ijọba ipinlẹ Ọyọ lọ sile ẹjọ latari bi wọn ṣe yọ ọ nipo lọna ti ko ba ofin mu.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI