O TAN O: ALAO-AKALA LOUN YOO ṢIṢẸ FUN APC LASIKO IDIBO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, March 2, 2019

O TAN O: ALAO-AKALA LOUN YOO ṢIṢẸ FUN APC LASIKO IDIBO

Bọsun Ọlaniyi, Abẹokuta 

Ṣe lọrọ naa kọkọ dabi awada nigba ti oludije sipo Gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Action Democratic Party, ADP, Ọtunba Christopher Adebayọ Alao-Akala sọ pe bo tilẹ jẹ pe digbi loun ṣi wa ninu ẹgbẹ oṣelu naa, ṣugbọn ṣa, oludije sipo Gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress Congress, Adebayọ Adekọla Adelabu loun yoo ṣiṣẹ fun.

Bi Ọtunba Alao-Akala ṣe gbe ọrọ naa sita lawọn eeyan ti bẹrẹ sii sọ pe ko daju pe ọkunrin to ti figba kan ri jẹ ipinlẹ naa labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party mọ nnkan to n ṣe mọ, ati pe olori ẹgbẹ awọn alagabangebe lo yẹ kawọn fi jẹ nipinlẹ Ọyọ.

Lọjọ Tọside ijẹta yi la gbọ pe Ọtunba Akala ṣepade bonkẹlẹ pẹlu Aṣiwaju ẹgbẹ oṣelu APC, Bọla Ahmed Tinubu niluu Eko, ipade naa ti iyawo Akala, Arabinrin Oluwakemi Alao-Akala; ọmọ ẹ, Ọlamiju ati alakoso eto ipolongo idibo ẹ, Wale Ohu ko gbẹyin la gbọ pe ṣe lati fi wa ojurere ẹ.

Nibi ipade naa la gbọ pe Aṣiwaju Tinubu ti beere lọwọ ẹ pe talo lẹnu ju laarin oludije sipo Gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP ati ti APC, to si ni Ṣeyi Makinde naa lẹnu, paapaa niluu Ogbomọṣọ.

Eyi lo mu ki Aṣiwaju sọ pe ko fẹgbẹ naa silẹ lati ṣiṣẹ fun Adebayọ Adelabu tẹgbẹ oṣelu APC, ti wọn si ṣeleri obitibiti owo fun un.

A gbọ pe Alao-Akala ko ro o lẹẹmeji to fi gba si Tinubu lẹnu pe oun yoo fi gbogbo ara ṣiṣẹ fun Adelabu lọjọ Satide to n bọ.

Akala ni lootọ l'oun ṣepade pẹlu awọn ẹgbẹ alatako bi PDP, ADC ati ZLP, ati pe Gomina Ipinlẹ Oyo tẹlẹ ri Raṣidi Ladọja lo ṣagbatẹru ipade ọhun.

Gomina ipinlẹ Oyo tẹlẹ Akala nigba ti ipade oun pẹlu ẹgbẹ awọn alatako n lọ lọwọ ni oun gba ipe lati ileeṣẹ Aarẹ.

AWIKONKO gbọ pe idi ti wọn fi ranṣẹ pe Alao-Akala lati bẹbẹ fun iranlọwọ ẹ ni bi Gomina ipinlẹ naa, Abiọla Ajimọbi ṣe padanu ipo Sẹnetọ ninu idibo to kọja lọ, latari gbogbo ileri to ti ṣe fun wọn pe ko nii si wahala, APC ni yoo gbajọba Ọyọ, ṣugbọn si iyalẹnu to jẹ pe PDP lo rọwọ mu.

Ohun tawọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu ADP, paapaa awọn adije labẹ ẹgbẹ oṣelu naa n sọ bayii ni  pe Ọtunba Alao-Akala ti gbabọdi fun wọn, ati pe gbogbo ọrọ to n sọ pe oun yoo ṣatilẹyin fun wọn lawọn ko nigbagbọ ninu ẹ mọ, nitori pe o ti dalẹ wọn nitori owo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI