Aarẹ ana lorileede Naijiria oloye Olusegun
Obasanjo ti parọwa si Seyi Makinde pe ki o yago fun oṣelu sọ sapo.
Arọwa yi waye nigba ti Makinde ati awọn ikọ rẹ
ṣabẹwo si Obasanjo nilu Abeokuta.
Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ rẹ Kehinde
Akinyemi fi sita Obasanjo gba Makinde lamọran pe ko''ma ṣe ba wọn kopa ninu oṣelu
ti yoo ṣanfaaani fun awọn apa kaan.''
Aarẹ ana ohun sọ pe Gomina ti wọn ṣẹṣẹ dibo
yan naa ni iṣe lati ṣe nipa mimu idagbasoke ba ipinlẹ Oyo to si tun kesi awọn
eeyan ipinlẹ naa lati gbaruku ti.
''Jẹ alakoyawọ ki o si dawọ le awọn akanṣe iṣẹ
eleyti ti yoo mu inu ara ilu dun.''
O sọfun pe o gbọdọ fun ara ilu ni nnkan to da
yatọ si ''eleyi ti aburo mi a ma pe ni oṣelu sọ sapo.''
''Jẹki wọn ma bere wi pe nibo ni iru ijọba yi
wa lati ọjọ yi.''
Obasanjo se'leri lati gbaruku ti ijọba tuntun
naa ati wi pe nigbakigba ti wọn ba nilo amọran ohun,oun yoo duro gẹgẹ bi baba
fun wọn.
Ninu ọrọ ti rẹ, Makinde ni abẹwo naa wa lati
dupẹ lọdọ Obasanjo ki ohun si beere amọran lọdọ agba oṣelu naa.
Yatọ si aarẹ Obasanjo, Makinde tun ṣe abẹwo
si alagba Fasoranti ati alagba Olu Falae nipinlẹ Ondo.
No comments:
Post a Comment