Ko si nnkan meji to mu ki
Ọtunba Gbenga Daniel, ti wọn tun n pe ni OGD loun ko ṣe oṣelu mọ bi ko ṣe ti
wahala to jẹyọ ninu ẹgbẹ oṣelu PDP lasiko to fi wa nijọba gẹgẹ bi i Gomina
ipinlẹ Ogun labẹ asia ẹgbẹ naa.
Ninu lẹta ti OGD kọ ranṣẹ si
alaga ẹgbẹ oṣelu PDP lapapọ, Ọmọba Uche Secondus lọjọ Tọside ijẹta, iyẹn ọjọ
kẹrinla oṣu kẹta, ọdun 2019, o ni ẹdun ọkan lo jẹ foun pe latigba ti wahala
ẹgbẹ naa ti bẹrẹ titi dasiko yi, ko sẹni to ri wahala naa yanju.
Ọjọ keṣan
an, oṣu kẹsan an, ọdun 2001 ni Ọtunba Gbenda Daniel darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu PDP
nibi ipade ipolongo ayẹyẹ nla kan fun oṣelu, eyi to jẹ malẹgbagbe nilẹ Yoruba,
latigba naa ni wọn ti gbẹrẹgẹjigẹ titi di ọdun 2003 ti wọn fi gba ilẹ Yoruba
fun ẹgbẹ oṣelu PDP.
Ninu lẹta
naa lo ti jẹ ko di mimọ pe ọdun mẹjọ toun lo gẹgẹ bi Gomina ipinlẹ Ogun, aritọkasi
nijọba oun titi dasiko yi, nipa awọn eto arambara nipa gbigbe ipinlẹ naa larugẹ
lẹka-o-jẹka.
OGD ni awọn
aṣeyori yi ni ko ṣeẹ gbagbe ninu itan ipinlẹ naa lati ọdun 1976 ti wọn ti da a
silẹ. Ati pe nigba ti wahala ẹgbẹ oṣelu PDP maa bẹrẹ lọdun 2009, iyẹn nigba ti
saa iṣakoso ẹ n kasẹ nilẹ, eyi to mu ki wọn padanu idibo ọdun 2003, to si jẹ ẹdun ọkan pe lati bi ọdun mẹwaa sẹyin titi dasiko yi, wahala naa
ko yanju.
Bẹẹ lo sọ pe lara nnkan to mu koun fi oṣelu silẹ ni
lati raaye fun ti ajọ alaanu toun da silẹ, iyẹn Gateway Front Foundation.
No comments:
Post a Comment