Gẹgẹ bi
iroyin to tẹ AWIKONKO lọwọ laipẹ ṣe fi to wa leti, adugbọ kan ti wọn n pe ni
Saraki, lagbegbe Adigbẹ niluu Abẹokuta niṣẹlẹ naa ti waye lọjọ Tọside, ọjọ
kejidinlọgbọn oṣu keji ọdun yi.
Ninu ẹkunrẹrẹ
iwadii ti AWIKONKO ṣe la ti gbọ pe ọdun 2006, tii ṣe ọdun mẹtala sẹyin ni Kẹhinde
ati Ibukun ṣe igbeyawo alarede, ti ọlorun si fi ọmọ mẹrin ta wọn lọrẹ, ṣugbọn
ti ọkan pada ku ninu awọn ọmọ naa.
A gbọ pe
nigba ti wahala yi maa bẹrẹ laarin awọn mejeeji, akọbi awọn mejeeji yi ko tii
pe ogoji ọjọ, iyẹn 41days ti wọn ni Kẹhinde ti bẹrẹ sii fi oriṣiriṣi ẹsun kan
Ibukun, to si maa n lu lalubami.
Wọn ni ẹsun
kan ṣoṣo ti Kẹhinde fi n kan iyawo ẹ ni ẹsun agbere, ati pe kii gbọnran soun lẹnu.
Wọn ni gbọgbọ ile tawọn mejeeji n gbe ni wọn fun wọn niwe pe ki wọn jade latari
wahala ojoojumọ wọn.
Awọn mọlẹbi
awọn mejeeji la gbọ pe wọn ti da si ọrọ wọn, ṣugbọn ti wọn ni aṣeju Kẹhinde ko
jẹ ko gbọnran sẹnikẹni lẹnu, to jẹ pe iwa tinu ẹ nikan lo n ṣe e.
Lara awọn to
b’AWIKONKO sọrọ lori iṣẹlẹ jẹ ko ye wa pe Ibukun lo n gbe bukata to pọ ju ninu
ile, nitori ti wọn ni Kẹhinde ko niṣẹ gidi kan lapa, ko si wa ọna bi aye ẹ yoo ṣe
yipada.
Wọn ni ẹẹmeji
ọtọọtọ ni Ibukun ti gba owo alajẹṣẹku fi ra mọto fun Kẹhinde ọkọ ẹ, ti ko si
nii da owo naa pada funyawo ẹ lati ko silẹ ni ẹgbẹ alajẹṣẹku to ti gba owo
jade.
Bẹẹ ni wọn sọ
pe yatọ si mọto meji yi, Ibukun tun ti ra ọkada fun Kẹhinde pe maa gun un nigba
to jẹ pe iṣekuṣe lo ṣe awọn mọto naa, to si ta a danu, to jẹ pe ṣe lo na owo jẹ,
bi iyawo ẹ ba si beere ohunkohun lọwọ, ija ni yoo gbe koo loju.
Nibi to le
de, Ibukun la gbọ pe o kọ ile ti wọn n gbe lagbegbe Adigbe yi, to si tun ti ra
ilẹ si agbegbe Ọbada niluu Abẹokuta bakan naa, ta a si gbọ pe agidi ni Kẹhinde
fi gba ilẹ naa lọwọ ẹ.
Wahala yi l’AWIKONKO
gbọ pe o gbe Kẹhinde to n ta ohun eroja ile kikọ kuro ninu ile lọdun to kọja,
to si lọọ gba ile sibomin in pẹlu iranlọwọ mama ẹ, ṣugbọn ti wọn ni Kẹhinde tun
maa n lọọ luu mọbẹ.
Lọjọ Tọside ọjọ kejidinlọgbọn oṣu keji tiṣẹlẹ buruku naa
waye, a gbọ pe ile min in ni Ibukun tun wa lọ lati gba,
nitori ti wọn lojoojumọ ni Kẹhinde maa n
lu mọle to n gbe, bo si ṣe n de la gbọ pe ẹja ti ẹgbọn mama n
ta lo fẹẹ ko wọle ni nnkan
bi aago mẹjọ alẹ
ọjọ naa ko too
di pe Kẹhinde yọ si lojiji, to si bẹrẹ sii ṣa a lada ni gbogbo ara.
Wọn ni kawọn to wa
nitosi too debẹ, Kẹhinde ti gbe ọkada ẹ salọ, awọn eeyan ni wọn sare gbe
Ibukun lọ si ọsibitu Hope
to wa nitosi lati doola ẹmi ẹ kuro ninu
agbara ẹjẹ.
Lẹsẹkẹsẹ ni wọn ti lọọ fọrọ naa to ọlọpaa leti, tawọn yẹn si bẹrẹ igbesẹ lati rii mu, nigba tọwọ maa tẹ ẹ, asiko to fẹẹ fi ilu Abẹkuta silẹ laṣiri ẹ
tu, to si wa
lagọ Ọlọpaa
titi dasiko ta a ṣakojọpọ iroyin yi
tan.
Ibukun, nigba to n b’AWIKONKO sọrọ lori bẹẹdi lọsibitu to ti
n gba itọju, o ni “Ki akọbi wa too pe
ọmọ ọjọ mọkanlelogoji
(41days) lo ti maa n lu mi, ọmọ yẹn si ti pe ọdun mejila
loṣu yi, ti n ba beere owo ounjẹ temi ati tọmọ lọwọ ẹ, wahala ni, ṣe lo maa tilẹkun, to maa
yi redio soke, ko too bẹrẹ sii lu mi kawọn araale ma baa gbọ ariwo,
igba to ya ni wọn le wa jade nile yẹn.
“Igba to ya, mo ra ilẹ, mo si kọ ile
sagbegbe Ọpako ni Adigbẹ, Abẹokuta, ile naa la jọ n gbe
bayii. Aarin oru lo maa n saba lu mi ju, aimọye igba ni
mo ti gbe oju wiwu lọ sọdọ awọn obi ẹ, ti wọn si maa bẹ mi.
“Lọjọ kan, oun ati
obinrin kan to n jẹ Iya Mubarak ja lori ọrọ owo ina,
obinrin yẹn si bu pe emi iyawo ẹ ni ko jẹ ko ni
laari, aarin oru lo fi ẹṣẹ ati ipa ji mi loju oorun pe ki wa n ṣalaye boun
ko ṣe ni laari. Mo ni bawo lo ṣe jẹ, emi kọ ni mo n ṣe e, ti m ba gba owo alajẹṣẹku, tabi kọmulelanta,
iwọ ni mo n koo fun. Ko sigba ti mo gba owo ele, iwọ lo maa gba
lọwọ mi pẹlu agidi, too si ni daa pada fun mi.
“Mo ra mọto akọkọ ati ekeji
fun ẹ, mo si tun ra ọkada fun ẹ, sibẹ
ṣe lo tun maa
lu mi. ko san owo ileewe awọn ọmọ ẹ ri, wahala
ni ti n ba beere lọwọ ẹ, igba (200) naira
lo maa n fun emi atawọn ọmọ mẹta pe ka fi jẹun, ẹẹkọọkan si ni.
“Ọsẹ mẹrin sẹyin lo lọọ fẹjọ sun pasitọ
ṣọọṣi
ti mo n lọ, ti wọn si pe mi, bi mo ṣe n ṣalaye gbogbo bọrọ naa ṣe jẹ fun wọn tan
lo de, pasitọ si beere pe ki lo fẹ ka ṣe, ko ri ọrọ gidi sọ, mo wa kuro
nibẹ, mo gba ṣọọbu mi lọ, oju ọna ni mo wa
to tun ti sare gbe ọkada pade mi, to bẹrẹ sii lu mi.
“To ba ti n lu
mi nita gbangba, ọrọ kan ṣoṣo
to maa n sọ fawọn eeyan ni pe iṣẹ oloṣo ati aṣẹwo ni mo n ṣe, eyi lo
maa n mu kawọn to ba fẹẹ gba mi silẹ lọwọ ẹ kuro nibi to ti n lu mi. Aarin ọdun to kọja lo bẹrẹ ko maa fi
ada lu mi, ti a si ti gbe
ẹjọ lọ teṣan. Oṣu mẹfa ni wọn
fun un pe ko gbọdọ de ṣọọbu mi mọ, depodepo pe yoo lu mi, ṣugbọn ko gbọ, o tun ṣi maa n wa lu mi nibẹ.
“Lọjọ Tọside tiṣẹlẹ yi ṣẹlẹ, iwaju ṣọọbu
ni mo wa ti ọlọkada kan to ran wa ti wa a fọgbọn tan mi pe oun fẹẹ ra nnkan, nitori pe mi o ki n jokoo si ṣọọbu mọ nitori ti ẹ, bi mo ṣe wọle ti mo maa
yi oju pada ni mo ba lẹyin mi, to si bẹrẹ sii lu mi,
igba to ya lo fi mi silẹ. Alẹ lo pada wa
to wa fi ada ṣa mi.
“Ẹgbọn mama mi ti mọ n ba ko ẹja ti wọn sa sita wọle lọjọ naa lo n pariwo
pe Baba Ayọ ti ṣa iyawo ẹ pa, kawọn
araadugbo wa a gba mi. Ki wọn too de, o ti
gbe ọkada salọ. A fi kawọn ọmọ Naijiria
gba mi lọwọ ẹ, ki wọn ma
jẹ kiya yi jẹ mi gbe, nitori pe mi o mọ nnkan ti mo
ṣe fun un, to fi n ṣe mi bayii.
Mi o le gbe foonu teeyan ba pe mi. Mi o mọ ibi kankan
niluu Abẹokuta, ọmọ Ileṣa ni mi, Eko
ni mo gbe dagba, Itoko niluu Abeokuta ni Kẹhinde ti wa.
Mo ra ilẹ sagbegbe Ọbada, o ni
mi o gbọdọ forukọ mi sinu risiiti
(receipt) pe orukọ oun ni ko wa nibẹ. Ọmọ mẹrin la bi, ẹyọkan ti ku.
“Lọjọ Mọnde
to kọja yi ni mo lọ si kọọtu lati ja iwe fun un, ti mo si lọọ fun niwe naa,
latigba to ti gba iwe kọọtu yi ni wahala naa tun ti gbọna min in yọ, to jẹ pe
iku mi lo n wa kaakiri. Ọlọrun ni ko pa mi. Ẹ gbami o.” Bayii ni Ibukun ṣe ṣalaye fun AWIKONKO.
Baba Ibukun,Ọgbẹni Kọlawọle Oluṣeyi naa tun b’AWIKONKO
sọrọ, o ni “Lootọ ọmọ mi ti maa n
wa fẹjọ sun pe ọkọ oun maa n fi pana lu oun, igba to pọ ju ni mo ni ki wọn
lọ si Human Right lati lọọ ja iwe fun.
Mi o si nile, ṣugbọn nigba ti mo maa pada de,
ti wọn ko lọ ni mo ki wọn lọ si ile ẹjọ kọkọ-kọkọ to wa ni Agbẹlọba lati lọọ jawe fun un.
“Ọjọ Mọnde to ku ọjọ mẹta kiṣẹlẹ naa waye ni wọn lọọ fun niwe ikọsilẹ, mo ro pe iyẹn lo tun bii ninu to fi ṣe nnkan to ṣe yi. Nnkan
kekere la kọkọ pe e nigba ti wọn
ranṣẹ pe mi,
afi ba a ṣe rii ninu agabra
ẹjẹ, to ti ṣa ọmọ mi yanna-yanna. Mo fẹ bẹ ijọba pe ki wọn
gba mi, nitori pe iya to fi jẹ ọmọ mi
yi pọ ju, kawọn ọmọ ati ijọba Naijiria
gba mi. Lootọ a ko leeyan ṣugbọn a ni Ọlọrun.”
Bakan naa, Mama Ibukun, Arabinrin Felicia
Adekolẹgan nigba to n sọrọ sọ pe “Ọpọ igba ni mo ti lọ sile wọn lọọ bawọn da si
ija wọn, igba to ya mo sọ fun ọkọ ẹ pe ko gbọdọ luu mọ, bi bẹẹ kọ, mo maa ko ẹru ẹ kuro nile. Igba ti ko gbọ, mo
lọ sibẹ, mo lọọ ko ẹru ẹ kuro, mo si
gba ile fun ọmọ mi. ojoojumọ ni Kẹhinde
tun n lọ sibẹ lọọ luu ni
aludaku.
“A lọọ fẹjọ sun ni teṣan Adigbẹ, o si fọwọ siwe pe oun
ko nii luu mọ, ṣugbọn ko gbọ.
Eyi to ṣẹlẹ gbẹyin yi, adugbo Kemta
Idi-Aba ni mo n gbe ki wọn too pe mi, igba ti mo maa debẹ, ọkan mi baje
pupọ, ṣe ni mo n sunkun nigba ti mo ba ọmọ bibi inu mi ninu agbara ẹjẹ, kawọn ọmọ Naijiria
gba mi o, ki wọn ma jẹ ki iya yi jẹ wa gbe o.”
Yoruba bọ, wọn ni ‘ba mi lu
ọmọ mi, ko de
inu ọlọmọ, ṣugbọn ọrọ ko ri bẹẹ nigba ti
Arabinrin Safurat Adebayọ Balogun to
jẹ iya Kẹhinde to ṣa iyawo sọ pe kijọba ba oun kọ
ọmọ oun lẹkọọ gidi, o ni
“Lootọ ni wọn maa n fẹjọ sun emi naa
pe Kẹhinde maa n lu iyawo, ti mo si ba bẹẹ. Lọjọ ti wọn wa
ba Ibukun ko ẹru, pati kan ni mo wa ti wọn ti pe mi. Ibi kan naa
lemi ati Mama Ibukun ti maa n ra ọja, o si maa
n fẹjọ sun mi, temi naa si ti pe e laimọye igba, ṣugbọn ko gbọ.
“Emi gan ko lẹmi awọn
nnkan ti iya Ibukun maa n ṣe fun wọn,
abiyamọ gidi ni. Igba ta a bẹbẹ titi, Baba Ibukun sọ pe o digba
ti Kẹhinde ba san owo tiyawo ẹ ba a ya
ninu ẹgbẹ alajẹṣẹku ko too pada sile, Iyawo lo lọ ya owo naa, ki ọkọ ẹ, Kẹhinde too fagidi gba a lọwọ ẹ, ti ko si daa pada.
“Ko sigba ti mo le pe ọmọ mi, ṣe lo maa sọ pe iyawo
oun n yan ale, o ti n fẹ ẹlomin in, mo
si maa n sọ fun un pe ko yee ṣọ iyawo ẹ mọ, ṣugbọn ko gbọ,
afi bi wọn ṣe sọ pe o ti ṣa iyawo ẹ pa, mo le jẹri sawọn iwa buruku ọwọ ọmọ
mi.
“To ba jẹ
ọmọ mi obinrin
ni ọkunrin kan ṣe bayii fun,
maa bẹ ijọba ki wọn da seria fun. Mo fẹ kijọba ran wa lọwọ, ki wọn ba
wa kọ ọ lẹkọọ to ba tọ si i.”
Kẹhinde nigba to n sọrọ sọ pe oun ko ti ẹ le sọ nnkankan nitori pe oun ko le sọ bo sẹ ṣẹlẹ nitori pe lẹyin toun huwa naa tan loju oun ṣẹṣẹ la. Bẹẹ lo rawọ ẹbẹ sijọba pe ki wọn foju aanu wo oun.
Kẹhinde nigba to n sọrọ sọ pe oun ko ti ẹ le sọ nnkankan nitori pe oun ko le sọ bo sẹ ṣẹlẹ nitori pe lẹyin toun huwa naa tan loju oun ṣẹṣẹ la. Bẹẹ lo rawọ ẹbẹ sijọba pe ki wọn foju aanu wo oun.
Lati fidi iṣẹlẹ
naa mulẹ, alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Ọgbẹni Abimbọla Oyeyẹmi to jẹ alukoro
ileeṣẹ Ọlọpaa sọ pe lootọ
ni, ati pe oun naa ṣẹṣẹ gbọ ni, ati pe Kẹhinde ti foju bale ẹjọ ẹjọ, ẹjọ naa ṣi
n lọ lọwọ.
No comments:
Post a Comment