ỌPỌ AWỌN OLOṢELU NI YOO KAGBAKO IJI NLA LỌDUN YI - WOLII IYUNADE - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, March 11, 2019

ỌPỌ AWỌN OLOṢELU NI YOO KAGBAKO IJI NLA LỌDUN YI - WOLII IYUNADE

Bọsun Ọlaniyi, Abẹokuta

Oludasilẹ ṣọọṣi Pentecostal Sanctuary Bible Ministries, Wolii Sunday Dare Iyuade ti gbe asọtẹlẹ nla kalẹ pe ọpọ awọn oloṣelu to n ni ijọba orileede Naijiria ni iji nla yoo gbe lọ, gẹgẹ bi omi ṣe gbe ọba Farao at'awọn ọmọ ogun rẹ lọ lọjọsi.

Wolii Iyuade lo sọrọ naa lonii Mọnde, ọjọ kọkanla oṣu kẹta ọdun 2019 nibi ipade to ṣe pẹlu awọn oniroyin lati fi saami ayẹyẹ ọdun kẹtalelogun ti wọn da ṣọọṣi naa silẹ, eyi to waye ni olu-ṣọọṣi naa to wa ni 9, Ararọmi Lane, Odo-Ẹgbọ niluu Ijẹbu-Ode, ipinlẹ Ogun.

O ni bo tilẹ jẹ pe oun ko mọ igba tabi akoko ti iji naa yoo ja, ṣugbọn Ọlọrun sọ foun pe iji nla kan yoo ja lagboole oṣelu, ti yoo si gbe lara awọn oloṣelu lọ, ati pe iji naa yoo mu ki awọn atunṣe wa kaakiri.

Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe "Ko nii si idibo to ja geere tabi esi ibo rere, ayafi ti ijọba to wa lori aleefa lonii ba kuro. Wọn kan maa fi awọn ohun alumọni wa ṣofo danu lasan ni. Ko si idibo to le gbe won kuro nipo, ayafi ti Ọlọrun funra rẹ ba yọ wọn danu. Ijọba yi yoo lo akoko rẹ pari, ṣugbọn ipaniyan ati itajẹsilẹ yoo pọ rẹpẹtẹ.

"Ijọba ologun ni ijọba yi yoo ṣe, ati pe awọn ologun ni wọn yoo pọ kaakiri orileede Naijiria.

"Ọlọrun sọ fun mi pe afẹfẹ iji oṣelu nla kan n bọ, ti yoo si gbe awọn oloṣelu kan lọ ni Naijiria. Mi o mọ igba tabi akoko ti yoo wa. Afẹfẹ iji nla naa yoo mu ki awọn atunto kan waye.

"Awọn aggbaagba nidi oṣelu kan yoo sọnu ki ọdun yi too pari. Ẹ jẹ ka maa gbadura fun awọn adari wa. Ijọba yi yoo lo agbara rẹ lati pọn awọn alatako rẹ loju. Wọn yoo tapa si ofin orileede yi. Ijọba nilo adura wa fun itọni atokewa.

"Mo ri okuta lọwọ awọn eeyan, ti wọn fẹẹ ju lodi sijọba."

Agba Wolii naa banujẹ gidi lori ipo ti iwa ajẹbanu wa lasiko ijọba yi, lo mu ko sọ pe pẹlu nnkan ti Ọlọrun fi han oun, awọn iwa ajẹbanu ti ko tii ṣẹlẹ ri ninu itan yoo ṣẹlẹ lasiko ijọba yi.

O wa a rawọ ẹbẹ s'awọn araalu pe ki wọn kun fun ọpọlọpọ adura nitori pe ọrọ iyan ti Ọlọrun sọ foun lọdun diẹ sẹyin ṣi n bọ, ki wọn si ma ba a ṣagbako ẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI