ỌWỌ FIJILANTE TẸ ỌRẸ MẸRIN TO N JI IRIN RELUWE TIJỌBA APAPỌ N ṢE LỌWỌ GE - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, March 16, 2019

ỌWỌ FIJILANTE TẸ ỌRẸ MẸRIN TO N JI IRIN RELUWE TIJỌBA APAPỌ N ṢE LỌWỌ GE

Kani ki i ṣe pe ọwọ awọn fijilante tijọba ipinlẹ Ogun, iyẹn Vigilante Service of Ogun state ko tẹ awọn ọrẹ mẹrin ti wọn sọ pe wọn ko niṣẹ meji ju ole jija lọ loru ọjọ Wẹside to kọja yi ni, o ṣeeṣe ki wọn ṣi maa jale naa siwaju lọ.

Ni nnkan bi aago kan oru ọjọ Wẹside naa la gbọ pe awọn adigunjale mẹrin yi lọ si Rafco to wa ni Cele Bluepoint, Agbado/Oke-Aro nipinlẹ Ogun, ti wọn si lọ n ge irin oju reluwe tijọba apapọ orileede yi n ṣagbatẹru ẹ lọwọ.

Nibi ti wọn ti n ge e laṣiri wọn ti tu sawọn oṣiṣẹ VSO to wa lagbegbe naa lọwọ. Bi wọn ṣe foju kan wọn ni wọn ba wọn wọya ija, ati pe nigba ti wọn ri i pe agbara wọn ko fẹẹ ka tawọn oṣiṣẹ VSO yi mọ, ni wọn ba salọ.
Bi wọn ṣe salọ ni wọn tun lọọ ṣepade lori bi wọn yoo ṣe fi owo tan awọn oṣiṣẹ VSO naa, ki wọn le gba fawọn lati ge irin tawọn fẹẹ ge lọ ta. Idi ni yi ti wọn fi pada lọọ ba wọn lati duna-dura, tawọn yẹn si sọ pe afi ki wọn foju bale ẹjọ.

Ni bayii, a gbọ pe ọga agba awọn fijilante naa nipinlẹ Ogun, Ọgbẹni Sọji Ganzallo ti paṣẹ pe ki wọ ko awọn ọdaran naa lọ sọdọ awọn sifu difensi lati tẹsiwaju lori iṣẹ naa. 
Alukoro ileeṣẹ VSO naa, Ọgbẹni Moruf Yusf to fi iroyin naa to wa leti jẹ ko ye wa pe lara awọn nnkan ti wọn ri gba lọwọ wọn ni awọn irinṣẹ ti wọn n lo lati fi ge irin naa, irin afẹfẹ gaasi (Oxy acetylene gas cylinder, One filled oxygen cylinder) ati kaadi idanimọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI