Kii ṣe iroyin tuntun mọ pe ayẹyẹ ọdun ilu ilẹ Afrika ti waye, o si ti kọja lọ. Ọjọbọ Tọside tii ṣe ọjọ karundinlọgbọn si ọjọ Satide Abamẹta to kọja yi, iyẹn ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣi yi ni ayẹyẹ naa waye, nibi ti orileede ti ko din ni orileede mọkanlelogun ti kopa ribiribi.
Titi dasiko ti ẹ n ka iroyin yi, lawọn eeyan kaakiri agbaye ṣi n sọrọ nipa ayẹyẹ naa, paapaa eyi to waye lọdun yi, iyẹn eyi to pari lọpin ọsẹ to kọja yi.
Awọn ẹgbẹ ti ko din ni mọkanlelaadọta (71) kaakiri ile adulawọ ni wọn kopa, tawọn to wa lati orileede Naijiria si jẹ mẹrindinlọgbọn (26). Yatọ sawọn orileede to wa kaakiri Afrika, awọn orileede bi United Kingdom, China, Belgium, Haiti, Germany ati France ni wọn ko gbẹyin nibi ayẹyẹ naa.
Bi wọn ba n sọ nipa ayẹyẹ iṣẹmbaye lagbaye, ko si bi wọn ṣe fẹẹ ya ayẹyẹ ọdun ilu ilẹ Afrika, African Drum Festival tijọba ipinlẹ Ogun n ṣagbatẹru ẹ lọdọọdun sẹyin.
Ninu ọrọ ti wọn sọ nibẹ, awọn
eekan Ọba alaye meji nilẹ Yoruba, Ọọni ile Ifẹ, Ọba Adeyẹye Ogunwusi, Ọjaja II ati
Alaafin tiluu Ọyọ, Ọba Lamidi Adeyemi III gba awọn to wa nipo aṣẹ lẹka iṣejọba
gbogbo niyanju lati rii wi pe wọn n ṣe koriya fun igbedide aṣa ilẹ Yoruba.
Ọọni Adeyẹye Ogunwusi ni idunnu
nla lo jẹ fun awọn ọbalaye lasiko yii lati rii pe ajinde n de ba awọn aṣa ilẹ
Yoruba.
"Ọpọ àṣà ilẹ kaarọ oojiire
ni o ti n lọ, ṣugbọn a dupẹ fun awọn ti Ọlọrun nlo lati gbee soke pada. Kani a
mọ pataki idagbasoke aṣa si idagbasoke eto ọrọ aje wa, a o tẹpa mọ .
Aṣa lo n siwaju ẹsin nitori aṣa
lagbara ju ẹsin lọ. Ilẹ kaarọ oojiire ni awokọṣe fun gbogbo agbaye.''
Ninu ọrọ tirẹ, Alaafin ti ilu
Ọyọ, Ọba Lamidi Adeyemi ṣalaye pe 'aṣa jẹ ọna kan gboogi lati ṣe aato ilu. Ti a
ba mu aṣa wa, a lee ko ilẹ Afirika jọ tii a o si fun wọn ni iwuri lati fi imọ
ṣọkan.'
Ni tirẹ, gbajugbaja onkọwe ni,
ọjọgbọn Wọle Soyinka rọ awọn ọba alaye lati maṣe kaarẹ lori awọn oloṣelu to n
ṣakoso ijọba bayii nipa gbigbawọn lamọran latigba de igba paapaa julọ lori
idagbasoke aṣa ati iṣe ilẹ Yoruba.
Ninu ọrọ tirẹ, Aarẹ Muhammadu
Buhari ti minisita fun eto iroyin ati aṣa, Alhaji Lai Mohammed ṣoju fun ni
iṣejọba to wa lode bayii ṣetan lati lo anfani to soodo si ẹka aṣa fun igbeleke
ọrọ aje awọn eeyan orilẹede naijiria.
Minisita feto iroyin ati aṣa
gboriyin fun awọn to gbe ayẹyẹ naa kalẹ pẹlu ileri atilẹyin ijọba apapọ fun
ijọba ipinlẹ Ogun lori ajọdun naa.
Diẹ re lara awọn fọto nnkan to ṣẹlẹ nibi ayẹyẹ tọdun yi.
No comments:
Post a Comment