NIBO NI TANTALA, KASNATY, ỌMỌỌDỌ AGBA, ỌMỌ BABA TIṢA, OLUMIDE AWOLỌWỌ ATI BABATUNDE ỌMỌBA WA NIBI AYẸYẸ IRANTI GBENGA ADEBOYE ATI TỌBA ỌPALẸYẸ??? - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, April 30, 2019

NIBO NI TANTALA, KASNATY, ỌMỌỌDỌ AGBA, ỌMỌ BABA TIṢA, OLUMIDE AWOLỌWỌ ATI BABATUNDE ỌMỌBA WA NIBI AYẸYẸ IRANTI GBENGA ADEBOYE ATI TỌBA ỌPALẸYẸ???

Bọsun Ọlaniyi, Abẹokuta

Bi ẹsẹ ko ṣe gbero to ninu gbọngan ayẹyẹ tawọn oniroyin to wa lagbegbe Oke-Ilewo niluu Abẹokuta lonii, nibi tẹgbẹ sọrọsọrọ to da duro, oyẹn Independent Broadcasters' Association of Nigeria, FIBAN ti ṣe iranti awọn akọni meji ti wọn sọ iṣẹ sọrọsọrọ di irọrun fawọn to wa nidi ẹ lonii, sibẹ awọn kan wa tawọn eeyan n beere nipa idi ti wọn ko fi yọju sibẹ.


Itan min in lẹgbẹ FIBAN tun fi balẹ lonii latari ọna ti ayẹyẹ naa gba waye, paapaa nigba tawọn agbaagba loriṣiriṣi ẹka ti wọn fiwe pe ko gbẹyin nibẹ, ti wọn pọn wọn le lati kopa.

Ọmọọdọ Agba, Kasnaty, Ọmọ Baba Tiṣa, Babatunde ọmọba, Tantala, Olumide Awolọwọ

Bo tilẹ jẹ pe pupọ ninu awọn alejo ti wọn pe pe ki wọn wa a kopa nibi idanilẹkọọ naa ni wọn ko fọkan si, to si jẹ pe ki eto naa to bẹrẹ lawọn kan ti beere lọwọ awọn to sunmọ awọn eeyan ta n sọ yi pe nibo ni wọn wa, ti ko si sẹni to le dahun ẹ.

Njẹ ẹ ti ka a? KI LẸ RATI NIPA GBENGA ADEBOYE ATI TỌBA ỌPALẸYẸ???

Ṣugbọn, iyalẹnu lo jẹ nigba ti Oludanilẹkọọ eto naa, Dọkitọ Goke Rauf maa kọkọ sọrọ, oun to sọ ni pe, inu oun ko dun rara lori awọn akiyesi toun ṣe, nitori pe awọn nnkan toun lero kọ loun ba pade.

Ọgbẹni Kọlawọle Adejojo tawọn eeyan mọ si Kasnaty; Oloye Mọruph Adegboyega, iyẹn Ọmọọdọ Agba; Oloye Sunday Ogunṣọla tawọn eeyan mọ si Tantala; Ọgbẹni Olumide Awolọwọ, Ọgbẹni Adeyinka Adegbitẹ, iyẹn Ọmọ Baba Tiṣa ati Ọmọba Babatunde Okunade lawọn tawọn eeyan n beere idi ti wọn ko fi yọju sibi eto naa.

Ẹ ma jẹ ko ya yin lẹnu pe awọn eeyan yi gan an ni wọn ba awọn akọni mejeeji yi jẹun papọ nigba aye wọn, nibi ti wọn sunmọ wọn de, eyi lo mu kawọn kan maa sọ pe ko yẹ kawọn eeyan yi ma si nibi eto iranti awọn oloogbe naa.

Nnkan to n jẹ kayeefi ni pe, lara awọn to sunmọ awọn eeyan gan an ko le sọ pato idi ti wọn ko fi yọju, tawọn kan si n sọ pe o ṣee ṣe ko jẹ pe ede aiyede to waye nigba diẹ sẹyin ni ko tii tan nilẹ, ṣugbọn ti ko ti ẹ sẹni to le sọ. 

Kasnaty
AWIKONKO gbọ pe latigba ọkunrin to kọṣẹ labẹ Yẹmi Ṣonde ti gba iṣẹ ileeṣẹ kan ta a forukọ bo laṣiri, to si ti n ri owo daadaa ni wọn lo ti n yẹra fun gbogbo nnkan to n ṣẹlẹ ninu ẹgbẹ FIBAN. Wọn ni gbogbo to ba nii ṣe pẹlu a n sọrọ eeyan lẹyin lọkunrin naa n yẹra fun, ti ko si fẹ ki wọn ri ọrọ ẹ sọ.

A ti ẹ gbọ pe Tọba Ọpalẹyẹ lo kọ ọga Kasnaty niṣẹ sọrọsọrọ, ti Kasnaty funra ẹ si maa n sọ pe ọrẹ timọtimọ loun ati Gbenga Adeboye, ati pe Gbenga Adeboye ko le ṣalai ma wa si ọfiisi oun to wa ni Kemta lẹyin to ba ṣeto tan lori redio OGBC, tawọn yoo si ṣe faaji.

Si iyalẹnu, Lori eto Kasnaty ṣe laipẹ yi, paapaa lori tẹlifiṣan OGTV pẹlu Alawiye lonii, wọn fi eto naa sọri awọn oloogbe mejeeji yi ni. Bi Alawiye ṣe kuro lori eto lẹyin ti wọn ṣetan, ibi ipade naa lo gba lọ, to si duro ti wọn fi pari lọọ ṣeto to kan.

 
Ohun tawọn kan n sọ bayii ni pe ko yẹ ki Kasnaty ma yọju rara, lati bu ọla ati iyi fun ọga-ọga ẹ, Tọba Ọpalẹyẹ, paapaa Gbenga Adeboye ti wọn jọ jẹ ọrẹ kori-kosun nigba aye ẹ.

Ọmọ-Ọdọ Agba (Imulẹ)
Awọn to sunmọ ọkunrin to gbajumọ daadaa pẹlu eto iriri aye yi gan an ko le sọ pato ibi ti ọkunrin yi wa dasiko ta a ṣakojọpọ iroyin yi tan.

Tantala
Bi ẹ ba beere lọwọ ọkunrin to n pe ara rẹ ni G.O ori redio leere pe talo fun un ni orukọ to n jẹ, ko sẹni meji ti yoo sọ bi ko ṣe Oloogbe Gbenga Adeboye lọ. Eyi gan an lo mu kawọn eeyan maa woye pe ki lo le ṣẹlẹ ti ọkunrin taye n gba ti ẹ lasiko yi ko fi yọju sibi iranti akọni to jẹ ki orukọ ẹ rinlẹ daadaa.

Olumide Awolọwọ

Ọkunrin yi yoo ri nnkan sọ lori ipa ti Gbenga Adeboye ati Tọba Ọpalẹyẹ ko nigbesi aye oun, paapaa nidi iṣẹ sọrọsọrọ to sọ ọ di olokiki. Ohun tawọn kan n sọ ni pe ko yẹ ti ọkunrin to maa n pariwo pe ẹgbẹ FIBAN ko fi laalaa ati wahala toun ṣe lati fi ja fun wọn yin oun, to si jẹ pe laipẹ yi ni wọn fi awọọdu nla kan da a lọla ma yọju sibi eto ti ẹgbẹ naa gbe kalẹ. Gẹdu Master lawọn eeyan tun n pe Olumide Awolọwọ to gbe apoti ọmọ ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ogun laipẹ yi, ṣugbọn ti wọle.

Babatunde Ọmọba
 
Ko si ọsẹ kan ki Ọmọba ma sọrọ nipa Oloogbe Tọba Ọpalẹyẹ lori redio, paapaa latigba to ti bẹrẹ eto to pe ni Ijẹun Agba, to si ni bata ti Tọba bọ silẹ loun gbe wọ, ati pe eto ti Oloogb Tọba Ọpalẹyẹ to kọ oun niṣẹ fi silẹ loun tẹsiwaju ẹ.

Iyalẹnu lo wa jẹ nigba ti a gbọ pe ọkunrin naa n bawọn kan binu, idi ni yii ti ko fi yọju sibi eto ti wọn gbe kalẹ lati fi ṣe iranti ọga ẹ. Wọn ni ko bojumu to, o si gbọdọ ṣe atunṣe lee lori.

Ọmọ Baba Tiṣa
 
"O maa too de, ko ni pẹ ẹ de" lohun tawọn kan n sọ nipa ọkunrin yi, ṣugbọn titi ti wọn fi pari eto naa ni wọn ko rii. Ko si sẹni to le sọ ibi ti ọkunrin ti wọn loo fẹẹ fi iwe kan lelẹ laipẹ yi wa lasiko ti eto iranti naa n lọ lọwọ.

Ọkan lara awọn to ṣagbatẹru eto naa, nigba to n b'AWIKONKO sọrọ, Ayinla Ẹgba sọ pe eto gbogbo ọmọ ẹgbẹ ni eto iranti Gbenga Adeboye ati Tọba Ọpalẹyẹ, ko si yẹ ko si idi kan ni pato ti ẹnikẹni to ba n pe ara rẹ lọmọ ẹgbẹ ma yọju sibẹ, ati pe gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ ni wọn gbọ nipa eto yi, ko da, ti wọn tun pe awọn eeyan lati wa a darapọ ṣayẹyẹ naa.

Ju gbogbo ẹ lọ, ibeere tawọn eeyan n beere ni pe "Nibo ni Tantala, Kasnaty, Ọmọọdọ Agba, Ọmọ Baba Tiṣa, Olumide Awolọwọ ati Babatunde Ọmọba Okunade wa lasiko ti eto iranti naa n lọ lọwọ, titi to fi pari?

Awọn eeyan lo n beere o, kii ṣe AWIKONKO

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI